Ondo state citizen killed in Jos: Ẹ̀gbọ́n tó jẹ́ arọ, bàbá tí kò lẹ́sẹ̀, ọ̀pọ̀ ìyàwó àti ọmọ ni àbúrò mi tí wọ́n pa ní Jos fi silẹ́ ní Ondo

Usman Tefiu, ẹgbọn ọkan lara awọn Fulani to fi ipinlẹ Ondo ṣe ibugbe ti awọn agbebọn Origwe, ni ariwa Jos, nipinlẹ Plateau pa lọjọ Satide, Maman Lawal, ti rọ ijọba lati yara lati mu awọn to ṣe ijamba ọun lati dena awọn ara ilu lati gbẹsan funra wọn.

Tefiu to ti padanu ẹsẹ rẹ mejeeji to si n fi ọpa rin lo sọ pe ohun ati baba ohun ti ko riran ni o nira fun lati gba iku Maman to padanu ẹmi rẹ lakoko to n pada sipinlẹ Ondo lati ipinlẹ Bauchi.

O ni bo tilẹ jẹpe o yẹ ki wọn ri iṣẹlẹ yi bii amuwa Ọlọrun gẹgẹ bii musulumi ododo, ṣugbọn awọn ti wọn ṣiṣẹ laabi ọun ni wọn gbudọ fimu kata ofin ki ọkan awọn to le e balẹ.

O ni oloogbe ọun lo fi aya meji ati ọpọ ọmọ silẹ fun ohun ẹgbọn rẹ ti ko lẹsẹ ati baba awọn ti ko riran.

" Mo ki aburo mi nilọ pe ko ma rinrinajo lọ si Bauchi lakoko yii, nitori eto aabo to mẹhẹ, amọ o faake kọri. O si lọ.

Ẹwẹ, Tefiu dupe lọwọ gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu fun igbesẹ rẹ lori iṣẹlẹ naa.

Darandaran miran, Abdulai Shu'aibu eni ti'o padanu ọmọ re sọpe ohun gbogbo ko sebẹ sẹnu're mọ lẹyin ti wọn sọ iroyin ibanujẹ nipa iku ọmọ re fun, ti o si kesi ijoba lati fi panpẹ ofin mu awọn ti o sekupa ọmọ rẹ.

Nibi ipade alaafia ti won se nilu Ibaram-Akoko, to wa ni ijọba ibilẹ Iwọ oorun-Ariwa Akoko, igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa to ṣoju Akeredolu ti sọ pe ijọba ipinlẹ Ondo ati Plateau n sisẹ takun-takun pẹlu awon ẹsọ alaabo lati fi panpẹ mu awọn to sọsẹ naa.

O parọwa fun wọn lati samuduro ibagbepọ alalafia ti wọn ni pelu awọn ara ilu naa pẹlu aridaju pe ijọba yoo pese abo ti o peye.

Akala tilu Ikaram-Akoko, Ọba Andrew Momoh sapejuwe iku awọn Fulani naa gẹgẹ bi adanu nla, bnitori pe bii ọmọ iya kan naa ni wọn jọ n gbe pọ.

Saaju abẹwo igbakeji gomina, awọ̀n Fulani naa ṣe akanṣe adura fun awọn to padanu ẹmi wọn pe "ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere, ko si fun awọn to wa nileewosan ni alaafia.