Àwọn èèkàn ẹgbẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá ní bí nǹkan ṣe rí pẹ̀lú àbò ní Nàìjíríà, bí aráàlú bá ní ìbọn fún àbò ara wọn kò burú o

Awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba kan ti sọrọ lẹyin ti gomina ipinlẹ Katsina, Bello Masari gba awọn ọmọ ipinlẹ rẹ nimọran pe ki wọn lọ ra ibọn lati daabo bo ara wọn.

Lara awọn ẹgbẹ naa ni ẹgbẹ Afenifere ati ẹgbẹ awọn agbagba ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders, YCE.

Ninu ọrọ ti wọn ba BBC Yoruba sọ, wọn ni o ṣeni laanu pe odidi gomina ipinlẹ lo n sọ fun awọn eeyan rẹ pe ki wọn lọ ra ibọn lati daabo bo ara wọn.

Wọn ni eyii n tumọ si pe gomina ọhun ti kuna ninu ojusẹ rẹ gẹgẹ bii ijọba, ati pe ijọba naa ti dojuru.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, akọwe agba ẹgbẹ YCE, Dokita Kunle Olajide sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ilẹ Yoruba bọwọ fun ofin gidi ṣugbọn asiko ti to fun wọn lati lọ ra ibọn fun abo ara wọn.

O ni "Asiko ti to fun awọn eeyan lati maa ra ibọn lati daabo bo ara nibi ti ọrọ de duro yii, ṣugbọn wọn gbọdọ gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa."

Olajide sọ pe "Ọmọ wa to ba fẹ ra ibọn, ko lọ gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba lati fi daabo ara rẹ, ko si ohun to buru nibẹ, ṣugbọn awa ko ni tẹ ofin loju mọlẹ."

Nigba ti ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ Afenifere, Bashorun Sehinde Arogbofa n da si ọrọ naa, oun naa sọ pe ko si ohun to buru nibẹ ti ijọba ba fi aye gba awọn araalu lati maa lo ibọn fun abo ara wọn.

O ni "O yẹ ki ijọba faye gba awọn eeyan ilu, paapaa awọn to kawe, ti ọpọlọ wọn pe lati maa lo ibọn."

Arogbofa sọ pe "Ṣe o tọ ki awọn ọdaran wọnyii ti wọn mọ ibọn n lo ka eeyan mọle ki eeyan ma le dabo bo ara rẹ ni?"

"Ṣugbọn ti awọn ọdaran naa ba mọ pe ẹni ti wọn fẹ lọ ba yii ni ibọn lọwọ, ati pe o mọ bi wọn ṣe n lo ibọn naa, wọn oo ronu wọn daadaa ki wọn to kọlu irufẹ ẹni bẹẹ."

Bo tilẹ jẹ pe baba Arogbofa ni ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu, ṣugbọn ijọba ti kuna ninu ojuṣe rẹ, idi ree ti awọn araalu fi ni lati bẹrẹ si n dabo bo arawọn.

O pari ọrọ rẹ pe ijọba apapọ ni lati ri awọn ọmọ Naijiria gẹgẹ bii ọkan ṣoṣo, ko si tun jawọ ninu iwa ẹlẹyamẹya, bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki nnkan buru ju bo ṣe wa yii lọ.

Ṣaaju ni gomina ipinlẹ Katsina, Bello Masari ti kọkọ ke si awọn eeyan ipinlẹ rẹ pe wọn ni anfani lati lọ ra ibọn lọna ati daabo bo ara wọn.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Abdu Labaran Malumfashi fi lede, o ni ọrọ eto abo kii ṣe ojuṣe ijọba nikan, awọn araalu naa ni lati ji giri sii.

O sọ ọrọ naa lasiko to n ba ẹbi awọn eeyan kan to jade laye lẹyin ti ọmọ awọn oni fayawọ gba wọn kẹdun.

Ẹwẹ, ọpọ awọn onimọ nipa eto abo lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ gomina ọhun.