Osinachi Nwachukwu Ekwueme's death: Èsì àyẹ̀wò ohun tó ṣekú pa gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu ti jáde- Ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa lolu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ni esi ayẹwo iku gbajumọ olorin ẹmi ni Osinachi Nwachukwu.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Abuja, Josephine Adeh fi sita ni esi ayẹwo ohun to ṣokunfa iku rẹ ti jade o, wọn si ti fi ṣọwọ si olupẹjọ agba fun ijọba nibẹ fun ayẹwo finifini ati pipe awọn to ba yẹ lẹjọ nile ẹjọ.

Amọṣa ileeṣẹ ọlọpaa ko sọ pato ohun ti esi ayẹwo iku gbajumọ olorin ẹmi naa sọ.

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Arabinrin Osinachi ti awo orin "Ekwueme" tan irawọ rẹ kariaye jade laye lọjọ kọjọ oṣu kẹrin ọdun 2022 lẹyin ti wọn ni o ni ọgbẹ inu lookan aya rẹnitori iya ati lilu lọwọ ọkọ rẹ.

Oniruuru ẹsun lawọn mọlẹbi arabinrin yii pẹlu awọn ọmọ ati awọn to sun mọ ọ fi kan kọ rẹ pe lilu bi baara nii maa n lu akọrin ẹmi naa lati igba ti wọn ti fẹra wọn.

Eyi ti fa ọpọ awuyewuye lorilẹede Naijiria lori iwa ifiyajẹ ọkọ tabi aya ẹni.

Awọn ọlọpaa fi panpẹ ofin mu Peter Nwachukwu, ọkọ akọrin ẹmi naa ti wọn si bẹrẹ iwadii lọgan lara eyi ti ṣiṣe ayẹwo iku rẹ ni ilana iṣegun oyinbo ti jẹyọ.

Lasiko ipade kan to waye laarin ọga ọlọpaa Naijiria ati minisita fọrọ awọn obinrin, Pauline Tallen atawọn mọlẹbi oloogbe naa, ileeṣẹ ọlọpaa fi da araalu loju pe iwadii finifini yoo waye lori iṣẹlẹ iku oloogbe Osinachi Nwachukwu, lati lee ri pe gbogbo awọn taje rẹ ba ṣi mọ lori finmu ko ata ofin.