Women waist beads: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ ìlẹ̀kẹ̀ ìdí

Otitọ ni pe wiwọ ilẹkẹ si ibadi fun oge ṣiṣe wọpọ laye igba kan.

Ṣugbọn iru aṣa yii ko ṣaaba wọpọ mọ laye ode oni.

Awọn ọdọmọbìnrin lo maa n ṣaaba wọ oriṣiiriṣii ilẹkẹ lati fi ṣe oge laye igba naa.

Ilẹkẹ ṣe pataki dé bi pe iru ilẹkẹ ti obinrin ba wọ ni yoo ṣọ bí yóò ṣe maa da awọn ọkunrin lọrun si.

Wọnyii ni iwulo ilẹkẹ ibadi ni wiwọ fawọn obinrin:

-Ami wi pe obinrin ni wọn ní ọpọ fi maa wọ ilẹkẹ si ibadi.

Ọkọ tabi ololufẹ obinrin to ba wọ ilẹkẹ ni yoo riri ilẹkẹ wiwọ julọ.

- Ilẹkẹ wiwọ tun maa n ṣe afihan pe ọdọmọbìnrin ti to ile ọkọ lọ.

Ilẹkẹ wiwọ tumọ si pe ọdọmọbìnrin le ni afẹsọna.

-abilekọ to ba wọ ilẹkẹ oni woroworo tumọ si pe ko ti mọ to fi ṣe igbeyawo.

-Wọn maa n wọ ilẹkẹ fun ọmọ ikoko lọjọ suna

Eyi wa lati jẹ ki ibadi ati itan ọmọ naa dagba daadaa.

- O le jẹ iyalẹnu fún ọpọ eeyan pe ilẹkẹ wiwọ si ibadi maa n wo aisan papaa julọ awọn ilẹkẹ to ba mi okuta iyebiye nidi.

Laye ode oni, eeyan perete ló maa n wọ ilẹkẹ si ibadi ṣugbọn maa n wọ ilẹkẹ si ọrun ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ kan tabi omiran.

Orisun ilẹkẹ wiwọ

Ọjọ ti pẹ ti awọn eeyan ti n lo ilẹkẹ.

Koda ilẹkẹ ti wa lati ọdun 15th sẹntiuri.

Ọpọ awọn onimọ gbagbọ pe ilẹkẹ wiwọ lati orilẹ-ede Egypt laye ọjọ-un

Wọn ní awọn obinrin to rẹwa lo maa n wọ ilẹkẹ nigba naa fún oge.

Lapa iwọ oorun ilẹ Afrika, awọn onkọtan ni awọn Yoruba lo sọ ilẹkẹ wiwọ di gbajugbaja.