Yoruba-Fulani crisis: Miyetti ní àwọn ò ní fààye gba kíkó oúnjẹ lọ sílẹ̀ Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Alakoso ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah ẹka ipinlẹ Kwara, Aliyu Mohammed sọ pe dide awọn ounjẹ ati maalu lati oke ọya silẹ Yoruba nipinlẹ Kwara yoo tẹsiwaju.

Mohammed ni ayafi ti aabo to peye ba wa fawọn Fulani nilẹ Yoruba ni awọn fi le dẹkun didena kiko ounjẹ ati maalu lọ síbẹ.

BBC Yoruba ṣabẹwo si ọja Bodija ki a mọ ohun to n ṣẹlẹ gan an ni pato:

Mohammed ṣalaye pe eyi jẹ ìkìlọ lati ri i pe awọn Fulani to wa nilẹ Yoruba n ṣe ọwọ wọn ni alaafia lai si pe ẹnikẹni n dunkoko mọ wọn.

O ni irọ ni ọrọ tawọn kan n gbe kiri pe ọdaran ni gbogbo awọn Fulani.

Mohammed ni ko si ẹya tabi ede ti ko ni awọn eeyan to dara at'awọn to buru, kii ṣe ninu ẹya Fulani nikan ni iru rẹ wa.

"Kii ṣe Fulani nikan lo n huwa ọdaran lorileede Naijiria, ṣugbọn ohun to buru ni pe Fulani nikan lawọn eeyan n sọ pe o wa nidi gbogbo laabi to n ṣẹlẹ ni Naijiria," Mohammed lo woye bẹẹ.

Alaga Miyetti Allah nipinlẹ Kwara ni ẹgbẹ ṣetan lati fa awọn Fulani ọdaran le awọn ọlọpaa lọwọ ni Kwara.

Mohammed ni "awọn fijilante wa n kaakiri igbo ijọba lati mu awọn ọdaran Fulani ti wọn n ba awọn Fulani darandaran jẹ.

Mohammed rọ ijọba apapọ lati fi ọwọ òfin mú Sunday Igboho lẹyin to ni kawọn Fulani fi ilu Igangan silẹ.