Zamfara abduction: Ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ní irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àwọn ti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà padà

Ijọba ipinlẹ Zamafara ti kede pe awọn agbebọn to ji awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ Government Girls Science Secondary School, Jangebe, gbe ko tii tu awọn akẹkọọ naa silẹ.

Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode lọsan ọjọ Aiku pe wọn ti tu awọn ọdọbinrin naa silẹ, ati pe wọn ti wa ni ikawọ ijọba.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Bello Muhammad Matawalle, Jamilu Ilyasu Magaji fi sọwọ si BBC, o ni irọ nla gbaa ni iroyin naa.

Irọ́ ni o! A kò tíì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó lé ní 300 tí wọ́n jí gbé ní GGSS Jangebe - Ìjọba Zamfara

Magaji ni "lati ọjọ Ẹti ti wọn ti ji awọn akẹkọọ naa gbe, gomina ati gbogbo awọn alabaṣiṣẹ rẹ ko tii sinmi nitori akitiyan lati wa awọn akẹkọọ naa ri."

"O ṣeni laanu pe awọn kan ti ko mọ ohun to n lọ le lọ gbe iroyin jade pe a ti ṣawari awọn akẹkọọ naa."

Magaji sọ pe irufẹ iroyin ti ko ni gbongbo bayii le ṣakoba fun akitiyan awọn ẹṣọ alabo to n wa awọn ọmọ naa, ati pe o le mu ibanujẹ ọkan ba awọn obi awọn akẹkọọ ọhun.

O pari atẹjade naa pe ijọba ipinlẹ Zamfara yoo bun awọn ọmọ Naijiria gbọ ni kete ti wọn ba ti ṣawari awọn akẹkọọ ọhun.

Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 317 gbé ní Zamfara

Lalẹ ọjọ Ẹti, iroyin jade wipe akẹkọbinrin meje ninu awọn ọọdunrun o le mtadinlogun ti awọn ajinigbe ji gbe ti bọ mọ wọn lọwọ.

Awọn araalu ti ipadabọ wọn ṣoju wọn sọfun awọn oiroyin pe wọn ti pada sinu ilu wọn funrawọn gẹgẹ bi wọn ṣe ni awọn kan dede wa ọna awọn lati pada sile nigba ti wọn n rin kiri ninu igbo aginju ti awọn ajinigbe gbe wọn lọ.

Gẹgẹ bi oṣojumikoro naa ṣe sọ, o ni awọn ọmọ naa ni awọn mii naa ti sa ti wọn yoo si to pada sile.

Gomina Matawalle paṣẹ ki wọn gbe gbogbo ileewe oniyara akẹkọọ ti pa ni Zamfara

Lẹyin ti iroyin ijinigbe yii tan ka gbogbo agbaye ti awọn ajọ ati orilẹede agbaye si ti n da si i ti wọn ti n fi ọrọ ranṣẹ si Naijiria, gomina ipinlẹ Zamfara ti paṣẹ pe ki wọn gbe gbogbo ileewe oniyara akẹkọọ ti pa ni Zamfara.

Bakan naa ni ọlọpaa ipinlẹ naa ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ri aridaju idoola awọn akẹkọbinrin naa.

Ọlọpàá ní iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GGSS Jangebe tí wọ́n jí gbé jẹ́ 317

Iroyin to ṣẹṣẹ n jade sita sọ pe awọn ajinigbepawo tun ti ṣọṣẹ ijinigbe ni ilu Jangebe ipinlẹ Zamfara.

Akẹkọọbinrin ni wọn tun ji gbe lọtẹ yii, wọn o si kere niye rara. Ṣaaju, iye ti wọn kọkọ sọ ni pe ọọdunrun ọmọbinrin ni wọn ti ji gbe.

Ko tii si aridaju kankan nipa awọn to ji awọn akẹkọ naa gbe bẹẹ si ni ko sẹni to mọ ibi ti wọn gbe wọn lọ.

Ẹwẹ, awọn ti ile iṣẹ iroyin BBC ba sọrọ sọ pe o daju wipe o le lọọdunrun awọn ọmọbinrin naa ti wọn jigbe nileewe ni Zamfara.

Baba ọkan lara awọn akẹkọ naa ati olukọ ni ileewe naa sọ fun BBC pe lootọ ni o ṣẹlẹ.

Oṣojumikoro sọ nigba ti wọ́n fi ka iye awọn ọmọ ile iwe naa to ku nilẹ ni wọn ri i pe irinwo lawọn ti wọn ko ri.

Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria naa royin rẹ pe Kọmisọna eto abo nibẹ, Abubakar Dauran sọ pe ọgọgọrun awọn ọmọ ileewe ni awọn agbebọn ti ji gbe l ṣugbn ti ko sọ iye wọn pato ni tirẹ.

Eyi waye ni ko pẹ ti akitiyan ṣi n lọ lọwọ lati doola awọn akẹkọọ Kangara ti wọn ṣẹṣẹ ji gbe lọsẹ to kọja.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Kabiru Sani ti wọn ji aburo rẹ mẹta gbe sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa yabo ileewe ọhun wọn si ko gbogbo awọn ẹṣọ alaabo ni papamọra ki wọn to ri awọn akẹkọọ naa gbe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "o ju ọọdunrun le aadọrin awọn obinrin ti wọn ji gbe ti awọn ọmọbinrin naa si wa lati ipinlẹ ọtọọtọ bii Kaduna, Sokoto, Kano, Jigawa ati Kebbi".

"Bi wọn ṣe de, wọn yi ileewe naa kaati gbogbo ibi ti wọn mọ pe awọn ẹṣọ alaabo wa wọn si kọlu ẹnu ibode ileewe, ẹṣ kan dide o si yinbọn amọ nigba to ri i pe agbara rẹ ju toun lọ, o sa lọ. Bi wọn ṣe rọna wọ yara awọn akẹkọbinrin naa ti wọn si n ji wọn ko.