LGBTQI in Ghana: Ààrẹ Ghana yarí pé ìjọba òun kọ́ ní yóò buwọ́lu ìgbéyàwó akọ sákọ àti abo sábo

Aarẹ Nana Akufo-Addo orilẹede Ghana ti sọ pe ijọba oun ko ni buwọlu igbeyawo akọ sakọ ati abo sabo.

Aarẹ Akufo-Addo sọ pe ti igbeyawo akọ sakọ ati abo sabo yoo ba tiẹ waye ni Ghana, kii ṣe labẹ ijọba oun.

Aarẹ sọrọ yii nibi ayẹyẹ ifinjoye biṣọọbu keji ijọ Angilika St Michael's ati All Angel's to wa ni Asante Mampong.

''Mo ti sọ tẹlẹ, ṣugbọn mo tun fẹ sọ ọ lẹkan sii pe kii ṣe lasiko ijọba Aarẹ Nana Addo Dankwah Akufo-Addo ni agbekalẹ ofin igbeyawo akọ sakọ ati abo sabo yoo ti waye,'' Aarẹ Nana-Akufo lo sọ bẹẹ.

Aarẹ Ghana ni ọpọ eeyan ati oriṣiiriṣii ajọ lo fẹ ki ijọba oun sọrọ lori iha to kọ si igbeyawo akọ sakọ ati abo sabo.

Ọrọ lori bo ya ijọba yoo buwọlu igbeyawo akọ sabọ ati abo sabo lorilẹede Ghana ti n ja ran-in-ran-in lori ayelujara laarin awọn ọmọ orilẹede naa lẹni ọjọ mẹta yii.

Ọrọ yii bẹrẹ lẹyin ti ijọgba gbe ile to da bi ọfiisi ẹgbẹ awọn akọ sakọ ati abo sabo ti wọn ṣẹṣẹ kọ ni Ghana tipa.

Lọsẹ to lọ ni ileeṣẹ ọlọpaa yabo ile ọhun ti wọn si gbe tipa niluu Accra, eyi ti ọpọ eeyan ni Ghana koro oju si.