Ọkùnrin kan, Enoch Adamu gún olólùfẹ́ rẹ̀, Ashini Hosea lọ́bẹ lórí N85,000 lẹ́yìn tó kọ̀ láti ṣèyàwó pẹ̀lú rẹ̀

Aawọ to wa laarin ọkunrin kan, Enoch Adamu ati ololufẹ rẹ tẹlẹ ri, Ashini Hosea bẹyin yọ lẹyin ti ọkunrin yii fa ọbẹ yọ nile ẹjọ ti o si bẹrẹ si ni gun obinrin naa.

Igbesẹ ileẹjọ to n ri si ẹsun ọdaran niluu Yola, ipinlẹ Adamawa to yi adehun to wa laarin ọkunrin naa ati ololufẹ rẹ pe obinrin naa gbọdọ san ẹgbẹrun marunlelọgọrin fun un lẹyin to sọ pe oun ko fẹ ẹ mọ.

Adamu gbe Ashini lọ sile ẹjọ lori adehun owo to wa laarin wọn pe yoo san fun un.

O fẹ gba gbogbo owo to ni oun ti na lori Ashini lati igba ti wọn ti n ba ọrọ ifẹ wọn bọ ki Ashini to sọ pe oun ko ṣe mọ.

Owo ori gan an wa lara owo ti Adamu fẹ gba pada lọwọ Ashini.

Ṣugbọn ileẹjọ wọgile adehun lati san owo naa pada fun Adamu.

Wọn gbe Ashini digba digba lọ si ile iwosan fun itọju nigba ti wọn ju Adamu si atimọle.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ileẹjọ ti kọkọ sun igbẹjọ ọhun si Ọjọbọ ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun 2021 lati jiroro lori owo ti Adamu n beere.

Ṣugbọn o ni ọrọ naa bẹyin yọ lẹyin ti agbẹjọro Ashini rọ ileẹjọ lati wọgile owo ti Adamu n beere fun nitori koro oju si ohun ti Adamu n beere fun.

Ẹni ti ọrọ ṣoju rẹ ni eyi gan an lo fa sababi iṣẹlẹ igunnilọbẹ nile ẹjọ.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe, DSP Sulieman Nguroje fidi rẹ mulẹ pe Adamu ti wa ni akolo awọn ọlọpaa.

Bakan naa ni Nguroje sọ pe Ashini si wa laaye, koda o fikun un pe Adamu tun gun awọn mẹrin miran lọbẹ ti wọn si farapa.