Kagara abduction: Lai Mohammed ní ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀

Faabada! Ijọba ko ni san owo kankan fawọn agbebọn ajinigbe to ji awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ ileewe girama Government Science College ilu kagara nipinlẹ Niger lọ,

Minisita eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed lo sọrọ lori ileeṣẹ ẹrọ amohunmaworan Channels.

Iroyin kan tu lu ayelujara pa pe ijọba apapọ ti san owo gọbọi fawọn ajinigbe lati fi awọn ọmọ akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ileewe ti wọn jigbe silẹ.

Amọ, nigba to n sọrọ lori eto kan lori Channels lọjọ Abamẹta, Mohammed ni irọ ni pe ijọba ti sanwo itanran fawọn ajinigbe.

Minisita ni oriṣiiriṣii ọna ni ijọba n gba lati rii pe awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ileewe Kagara ti wọn jigbe gba ominira.

Ọgbẹni Mohammed sọ pe ọjọ kan kọ ni gbogbo nkan de ibi to de yii, bakan naa ni kii ṣe ọjọ kan ni gbogbo nkan maa pada bọ sipo.

''Ijọba ko ni gba iwa ọdaran kankan laaye lorilẹede Naijiria, ati pe ijọba fẹ ṣe iwadii ohun to ṣe okunfa iwa ọdaran tawọn eeyan kan hu lawujọ.

Laipẹ yii ni mo lọ si ilu Minna pẹlu awọn minisita mii to fi mọ ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lati ṣe iwadii lori ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe ileewe girama Kagara.

Mo le fi da yin loju pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun lori ọrọ naa,'' Mohammed lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello paṣẹ l'Ọjọru pe ki wọn gbe gbogbo ileewe tipa lagbegbe tawọn ajinigbe ti n ṣọṣẹ nipinlẹ naa.

Ile igbimọ aṣofin l'Abuja naa ti sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ki o kede nkan o fara rọ lori ọrọ eto abo ni Naijiria.

Ṣaaju iṣẹlẹ yii awọn ajinigbe kan yabo ileewe girama to wa ni Kankara, nipinlẹ Katsina nibi ti wọn ji awọn akẹkọọ to le ni ọdunun un gbe lọ.