Orlu crisis video: Ohun tí a mọ̀ nípa fídíò tó lu ayélujára pa rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ṣé lóòtó ni ilé-iṣẹ́ ológun gbé hẹlikópítà ìjagun lọ si Orlu ní ìpínlẹ̀ Imo?

Iwadii BBC lori iroyin to sọ pe ileeṣẹ ologun orile-ede Naijiria n fi baalu ijagun hẹlikopita yin ado oloro si ilu Orlu fihan pe otitọ ni ileeṣẹ ologun gbe hẹlikopita lọ si Orlu nipinlẹ Imo.

Ni bi ọsẹ mẹta sẹyin lawọn janduku kan ṣekupa awọn eeyan ti wọn sì tun dana sun ọpọ ile níbẹ.

Oju opo Twitter ati Instagram ni Naijiria n gbona giri giri pẹlu iroyin pe ileeṣẹ ologun n yin ado oloro ni Orlu ti wọn si tun n mawọn ẹṣọ alaabo apa ila oorun Naijiria, Eastern Security Network (ESN).

Oriṣiiruṣii fidio lori Twitter lo n ṣafihan bi baalu hẹlikopita ṣe n fo kaakiri ilu Orlu.

Iro ibọn n dun nínu ọkan lara fidio to lu ayelujara pa bi hẹlikopita ṣe n fo.

Bakan naa ni ọkunrin kan n pariwo "ha! Jesu Kristi o! Kilode tawọn eeyan yii fi n kaakiri... Jesu ẹ wo ibọn. Ha!...ẹ jẹ ki onikaluku sare wọ ile o."

BBC ko le sọ ni pato igba ti wọn ya fidio ọhun tawọn eeyan n pin lori ayelujara.

Amọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, Orlando Ikeokwu sọ fun BBC pe oun o mọ ohun kan nipa fidio naa.

"Ọpọ eeyan lo ti n pe mi ti wọn si n beere ohun to n ṣẹlẹ ni Orlu, ṣugbọn ohun ti mo mọ ni pe ko si rogbodiyan kankan ni Orlu, alaafia ni gbogbo eeyan wa ni Orlu," Ọgbẹni Ikeokwu ṣalaye.

Odz Chioma to sọrọ lati ilu Orlu ṣalaye pe ko si rogbodiyan kankan lagbegbe oun.

Chioma sọ pe lootọọ lawọn ologun duro wamu wamu kaakiri ilu Orlu ṣugbọn wọn o ṣe idiwọ fun ẹnikẹni.

Awọn eeyan mii to tun sọrọ lati Orlu ṣalaye pe awọn gbọ iro ibọn lagbegbe Okporo, awọn si tun ri awọn sọja ṣugbọn ko si rogbodiyan kankan.

Awọn miran tun sọ pe agbegbe Uli ati Orsu lawọn ti gbọ iro ibọn, àmọ́ kò de agbegbe awọn.

Kinni ileeṣẹ ologun sọ?

Alukoro ileeṣẹ ologun 34, Artillery Brigade to wa ni Obinze, Owerri, Babatunde Zubairu sọ pe lootọọ lawọn gbe baalu hẹlikopita lọ si Orlu amọ awọn omogun awọn o dunkoko mọ ẹnikẹni.

Ọgbẹni Zubairu ni ileeṣẹ ologun gbe Igbesẹ yii nitori ohun ti wọn gbọ.