You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Shasha crisis aftermath: Alága àwọn òntàjà lóun pàdánù N20m níbi ìjà tó ṣẹlẹ̀
Ọpọ ẹmi ati dukia ni iroyin sọ pe o ṣofo nibi ija to waye lọja Sasha n'Ibadan nipinlẹ Oyo.
Koda, iroyin ni pe alaga ẹgbẹ awọn ontaja lọja naa, STA, Alhaji Usman Nyako ṣalaye pe oun padanu owo to le ni ogun miliọnu naira nibi ikọlu náà ni ijọba ibilẹ Akinyẹle.
Alhaji Nyako to ti jẹ alaga awọn ontaja lọja Sasha fun ọdun mẹta bayii sọ pe oun ko ni pada si ọja naa bi wọn ba tiẹ yanju aawọ ọhun tan tori ohun ti oju oun ri lasiko aawọ naa.
- "Èèyàn mọ́kànlá ni a yìnbọn pa níbi ìdigunjalè Offa"
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ pálábá Abubakar, mọ́káliíkì ségi níbi tó ti fẹ́ jí ọkọ̀ gbé l'Abuja
- Ìjọba Naijiria ti kùnà lórí ojúṣe rẹ̀ lóri ètò aàbò- Bode George
- Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
Oniṣowo Nyako ni owo to le ni miliọnu mẹwaa naira loun pa ninu ṣọọbu oun lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
"Ile mi, awọn ọkọ ti mo ni at'awọn ọkọ akẹru mi ni wọn dáná sun," Nyako ṣalaye.
Alhaji Nyako to sọ pe aṣọ toun wọ jade nile lo wa lara oun lọjọ náà gboṣuba fún ijọba ipinlẹ Kano fún ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira owo iranwọ to fún ìgbà eeyan to jẹ ọmọ bibi ipinle naa ti iṣẹlẹ ọja Shasha ṣakoba fun.
"Ọpọ eeyan ni wọn ṣekupa loju mi, nitori naa mi o le pada sibẹ mọ," Nyako lo sọ bẹẹ.
O ni iwa aisotitọ awọn eeyan kan lo ṣe okunfa rogbodiyan naa.
Alhaji Nyako rọ gbogbo ẹka ijọba lati dide iranwọ fún gbogbo àwọn tí iṣẹlẹ ọhún ṣe akoba fún.
Oniṣowo mii, Kabiru Tambuwal ṣalaye pe miliọnu kan naira loun padanu ninu rogbodiyan ọja Shasha.
"Ata ni mo n ta, awọn ọrẹ mi wa lara awọn to ku nigba ti ọpọ ti ori ko yọ ti pada si ilu Kano," Tambuwal ṣalaye.
Oun naa sọ wí pe oun o le pada si ọja Shasha mọ.
- A fẹ́ kí ìjọba fòfin de àwọn darandaran tó máa ń fi ìbọn Ak47 da málúù láàrín ìlú- MURIC
- Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano ṣèrànwọ́ ₦18.5m fún àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó faragbá nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
Ganduje ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ bíbí ìlú Kano 185 pẹ̀lú ₦18.5m
Gomina Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano ti gbe owo to le ni milliọnu mẹjidinlogun naira kalẹ fun awọn ọmọ bibi ilu Kanọ marunlelọgọsan (185) ti wọn padanu nnkan ini wọn sinu rogbodiyan to ṣẹlẹ ni ọja Ṣaṣa nilu Ibadan.
Alhaji Garba Mohammed, kọmiṣọnna fun iroyin nipinlẹ Kano to le iwaju awọn aṣoju ijọba ipinlẹ naa lo fun ọkọọkan ninu awọn eeyan naa ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira l'ọjọ Iṣẹgun nilu Ibadan.
Lara awọn to tun ṣoju ijọba ipinlẹ Kano nibi ipejọpọ naa ni Alhaji Ibrahim Muktar to jẹ kọmiṣọna fun karakata ati idokowo, ati Alhaji Sanusi Muhammed to jẹ kọmisana fun eto ẹkọ.
- Níléèwé girama GSS Kagara, àwọn agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ́, jí ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ míràn àti olùkọ́ gbé ní Niger
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn
Mohammed ṣe alaye pe gomina ipinlẹ Kano lo paa laṣẹ fun wọn lati ṣe abẹwo si awọn ọmọ bibi ipinlẹ naa ki wọn le ri i bi nnkan ṣe n lọ fun wọn ati ọna ti ijọba lẹ gba ran wọn lọwọ.
O ni, "Awọn eeyan bi i marunlelọgọsan an lo fara gba nibi iṣẹlẹ buruku naa, a ti ṣe iṣiro wa, eyii lo si mu ki a fun ọkọọkan wọn ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira.
"A o ṣe awari awọn to ti rinrin ajo lọ si Kano ninu wọn, bakan naa ni a o fi ọrọ naa to gomina leti lori bi a o ṣe ri awọn eeyan naa ti a o si fun wọn ni owo ti wọn."
O tẹsiwaju pe awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Kano ti ba awọn eeyan ti ọrọ naa kan sọrọ, wọn si ti gbọ alaye lori irora ati awọn ipenija wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣeleri wi pe awọn yoo fi ọrọ naa to gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde leti.
Kọmiṣọnna naa pe fun ifọwọsọwọpọ laarin awọn gomina ati awọn ajọ eleto aabo, gẹgẹ bi o ṣe n fi idunnu han wi pe kan yoo tun waye nipinlẹ Ogun lori eto aabo.
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Agbaṣẹ́ṣe jẹ búlálà méjìlá lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ẹlikọ́pítà kan pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá kògbérégbè ṣọwọ́ sí ìpínlẹ́ Oyo
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu ti paṣẹ pe ki wọn fi ikọ awọn agbofinro kan to dantọ ṣowọ si ipinlẹ Oyo lẹyin rogbodiyan to waye ni ọja Sasa to wa niluu Ibadan.
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Níléèwé girama GSS Kagara, àwọn agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ́, jí ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ míràn àti olùkọ́ gbé ní Niger
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣe naa, Frank Mba fi lede, o ni lara awọn ẹka agbofinro ti wọn n ran lọ si ipinlẹ naa ni awọn akọṣẹmọṣẹ lati ẹka ti wọn ti n fimu finlẹ, awọn ọlọpaa kogberegbe, pẹlu ẹlikọpita kan.
Atẹjade ọhun ṣalaye pe ojuṣe ikọ naa ni lati da alaafia pada si ipinlẹ Oyo, ki wọn si pana ija ẹlẹyamẹya to n jo nibẹ.
- A san owó f'áwọn sọ́jà tó dóòlà ẹ̀mí wa ní Sasa ká tó sá àsálà- Oníṣòwò Hausa
- Àwọn darandaran ṣekúpa èèyàn mẹ́ta lẹ́yìn àbẹ̀wò àwọn aṣojú ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Wọ́n ti kéde Ngozi Okonjo Iweala gẹ́gẹ́ bíi alákóso WTO
- A ṣetán láti ṣèwádìí àwọn ọlọ́pàá tó fìyà jẹ àwọn tó ṣewọ́de ní Lekki tollgate- Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "igbakeji adari ileeṣẹ ọlọpaa, DIG David Folawiyo ni yoo dari ikọ naa, ti yoo si ṣiṣẹ papo pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan lati da alaafia pada si ipinlẹ Oyo."
Adamu wa fi da awọn eeyan ilu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo sa gbogbo ipa rẹ lati ri daju pe ko si rogbodoyan kankan mọ nipinlẹ Oyo ati kaakiri Naijiria.
Lẹyin naa lo ke si gbogbo olugbe ipinlẹ Oyo atawọn ọmọ Naijiria miran lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro ki alaafia le jọba laarin ilu.
Ṣaaju ni gomina ipinlẹ ọhun, Seyi Makinde, ati ojugba rẹ nipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kọkọ ṣabẹwo si ọja naa lọna ati wa ojutu si rogboyan to bẹ silẹ larin ẹya Hausa ati Yoruba ninu ọja ọhun.
Gómìnà Makinde, Akeredolu ṣàbẹ̀wò sí ọjà Sasa, ṣèlérí ìrànwọ́ fáwọn tó fara kásá níbẹ̀
Gomina ipinlẹ Ọyọ ni igbesẹ arẹmọlẹkun yoo waye fawọn eeyan to padanu dukia ati ọrọ aje wọn sinu wahala to bẹ silẹ lọja Sasa lopin ọsẹ to kọja.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu pẹlu rs awọn eeyan lati ṣe ọpọlọpọ suuru nitori fifi waduwadu bi ilu ṣe ri mọ ibagbepọ awọn ataladugbo wọn lee ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.
Gomina Makinde pẹlu Akeredolu sọrọ yii nigba tawọn mejeeji kọwọrin lọ si ọja Ṣaṣa lati foju ganni ọwọja wahala naa.
Gomina Makinde ni lootọ iwe ofin orilẹede Naijiria fi aye silẹ fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati gbe ni ibikibi to ba wu wọn lorilẹede Naijiria, sibẹ eeyan bẹẹ gbọdọ tẹle ofin ati aṣa irufẹ agbegbe bẹẹ.
"Bi awọn janduku ba fẹ lo anfani bi ilu ṣe ri lati da rogbodiyan silẹ, a ko ni faaye rẹ silẹ. Mo ti pe ipade laarin awọn aṣiwaju igun mejeeji lati lee wọna abayọ lori iṣẹlẹ naa"
Gomina ipinlẹ Ọyọ fi kun un pe aṣẹ konile o gbele to wa nilẹ nibẹ yoo ṣi maa wa lọ nigba ti o si tun rọ awọn agbofinro lati jawe sobi lori ojuṣe mimojuto abo lagbegbe naa.
- Ẹ fura o! Nàìjíríà ń pín lọ díẹ̀ díẹ̀ rèé- Abdulsalami
- A fẹ́ kí ìjọba fòfin de àwọn darandaran tó máa ń fi ìbọn Ak47 da málúù láàrín ìlú- MURIC
- Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
Ninu ọrọ tirẹ, gomina Akeredolu rọ gbogbo awọn igun ti ọrọ kan lati sinmẹdọ.
A mọ pe ibinu wa lọkan awọn eeyan nilẹyii lọwọ ṣugbọn ẹ jẹ ka ṣe suuru. Lootọ iṣoro kan tabi omiran lee wa ṣugbọn otitọ ibẹ ni pe ọmọ iya ni gbogbo wa."
Lọjọ Ẹti ni ina wahala sọ ni ọja Sasa nilu Ibadan. Oniruru alaye lo ti n waye lori ohun to ṣokunfa rogbodiyan
Ki ni Aarẹ Buhari sọ
Aarẹ Buhari ti bu ẹnu atẹ lu oniruuru ikọlu to n waye lorilẹede Naijiria.
O ni asiko to fun awọn olori ijọ ẹsin atawọn ọbalaye, awọn gomina atawọn aṣiwaju oloṣelu miran gbogbo lati fọwọsowọpọ pẹlu ijsba apapọ lọna ati lee ri daju pe ko si ipinya ẹlẹsinjẹsin tabi ẹlẹyamẹya lawọn ilu to wa labẹ akoso wọn.
"Ijọba wa ṣetan lati daabo bo gbogbo ẹsin ati ẹya lorilẹede Naijiria bi o ti wu ki wọn mọ ni iye, ni ibamu pẹlu ilakalẹ iwe ofin Naijiria. A ko ni faye silẹ fun ẹya tabi ẹsin kan lati bẹrẹ si nii gbin ẹso wahala ati ikorira sawọn miran."