Valentines day Proposal 2021: Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Lojiji ni ọmọbirin kan deede di gbajumọ ọsan gangan lẹyin ti fidio ibi to ti ya were ti fa ori ayelujara yu lọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2021, to jẹ ayajọ ọjọ ololufẹ lagbaye.

Ninu fidio naa, ọrekunrin rẹ dẹnu ifẹ kọ ọ, o si fi oruka ifẹ bere lọwọ rẹ pe ṣe yoo gba ki oun fi ṣe aya, ṣugbọn kaka ko gba, tabi kọ oruka naa, ni ṣe lo deede ya were, iyẹn gẹgẹ bii fidio naa ṣe ṣafihan rẹ.

Ṣugbọn gẹgẹ bii ohun ti arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Odudu Grace sọ loju opo Instagram rẹ, o ni apara lasan ni fidio naa jẹ, ati pe oun ko ya were rara.

Ọjọ to tẹle ayajọ ọjọ awọn ololufẹ naa ni fidio ọhun bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara.

Omidan naa, to jẹ ọkan awọn to maa n ṣe fọran alawada lori Instagram sọ pe oun ko ya were, ṣugbọn ere lasan ni oun n ṣe ninu fido ọhun.

Lẹyin naa ni ọkan lara awọn to n tẹlẹ loju opo Instagram rẹ to mọ daadaa tun fidi ọrọ rẹ mulẹ pe apara lasan ni ohun to ṣẹlẹ ninu fidio naa.

Ẹwẹ, ọpọlọpọ eeyan lo gbagbọ pe lootọ ni omidan naa ya were lọjọ ayajọ ololufẹ lagbaye.

Koda, awọn miran tilẹ n pin fidio ọhun lori ikanni WhatsApp wọn, ti wọn si n kilọ pe ki awọn ọmọge aye ode oni ṣora ṣe pẹlu ọkunrin.