Lórí Irọ́: Ilúmọ̀ọ́ká oníṣòwò fún bàbá "Lórí Irọ́" lẹ́bùn owó gọbọi

Ọtitọ lọrọ awọn agba to wi pe ba ọ ku, iṣe o tan.

Ọrọ ti Ọgbẹni Gbadamosi Ismail ti ọpọ mọ si baba Lori Irọ sọ pe Eledua ti fi iran han oun ninu ala pe oun yoo di ilumọọka ti n wá sí imuṣẹ bayii o.

Ọpọ lo ti n sọrọ baba yii lori ayelujara fun bi ọjọ diẹ sẹyin bayii.

Iyẹn nikan kọ o, ni bayii, gbajugbaja onisowo kan ti fun baba lori irọ ni ẹbun ẹgbẹrun lọna igba owo naira(₦200,000).

Ko tan sibẹ o, oniṣowo yii tun fun baba Lori Irọ ni ẹbun foonu to to ẹgbẹẹrun owo naira.