You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Benin Republic: Ìjọba sọ̀rọ̀ lórí ìròyin tó ní Benin fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà
Ọpọ ọmọ Naijiria lo sọ ero wọn boya wọn fẹ ki orilẹede Benin Republic di ọkan lara awọn ipinlẹ to wa lorilẹede yii.
Niṣe lori ayelujara gbona giri giri lẹyin ti ọgọọrọ eeyan n gba ọrọ naa bi ẹni n gba igba ọti lori Twitter ati Facebook lọjọ Satide.
Iroyin kan lo kọkọ sọ pe minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama ṣalaye pe Aarẹ orilẹede Benin, Patrice Talon sọ erongba rẹ pe awọn ṣetan lati di ipinlẹ kẹtadinlogoji ni Naijiria.
- Wo obìrin méjì tó ń fi ìbásùn inú yìyín "Snow" ṣara rindin kí ọlọpàá tó ká wọn
- Ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára dá Shina Peters lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó kú
- Coronavirus ti ṣekúpa èèyàn 1,831 ní Nàìjíríà báyìí- NCDC
- Àwa ìpínlẹ̀ fúnra wa ló yẹ ká máa ṣàkóso inú igbó wa - Àfẹnukò àwọn gómìnà àti àwọn Ọba Yorùbá
- Awolọwọ ní tí àsìkò bá tó, ọ̀dọ́ á jà fúnra wọn- Sunday Igboho
- Ikú Ọ̀mọ̀we Fatai Aborode tí wọ́n pa ní Ibarapa lọ́wọ́ òṣèlú nínú - Makinde
- Fáàbàdà! Ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀- Lai Mohammed
- Bí ẹranko igbó ṣe bu ìdí obìnrin kan tó ń bẹ̀rẹ̀ yàgbẹ́ jẹ
Amọ, awọn Naijiria sọ ti inu wọn lori Twitter ati Facebook lori ọrọ naa.
Ọpọ eeyan lo sọ pe kaka ki kiniun ṣe akapo ẹkun, ki onikaluku maa ṣe ọdẹ tiẹ lọọtọọ.
Wọn ni ọrọ Naijiria gan an ti too gbọ, wọn sọ pe ki orilẹede Benin wa laye rẹ.
Sẹnẹtọ Shehu Sani atawọn ọmọ Najiria mii faramọ pe ki Benin Republic darapọ mọ Naijiria.
Ṣugbọn Sani ṣe ikilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ tumọ ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ ni Naijiria lede Faranse fun awọn eeyan Benin.
Ẹka ileeṣẹ ijọba orilẹede Naijiria to n ri si ọrọ ilẹ okeere ti fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ pe Benin Republic fẹ di ipinlẹ kẹtadinlogoji ni Naijiria.
Ninu atẹjade to fi sita loju opo Twitter rẹ, ilẹẹṣẹ ijọba naa ni orilẹede Naijiria ko ni erongba lati sọ Benin di ọkan lara ipinlẹ ni Naijiria.
Ijọba sọ ninu atẹjade ọhun pe awọn kan lo ṣi ọrọ ti minisita ọrọ ilẹ okeere sọ gbọ.
Atẹjade ọhun ṣalaye pe ohun ti Ọgbẹni Onyeama sọ ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati aarẹ Benin fẹ ki ajọṣepọ to wa laarin Naijiria ati Benin tun dan mọran sii.