Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ

Ilu Badagry kun fun ọpọ itan to nii se pẹlu owo ẹru, a ko si lee sọ itan owo ẹru ni Naijiria lai ma darukọ Badagry.

Lara awọn ohun manigbagbe to nii se pẹlu owo ẹru to wa ni Badagry ni ọpọ kanga ti awọn ẹru gbẹ.

Lasiko irinajo wa naa, a ri kanga agboole Seriki Abass, ti wọn kọ lọdun 1847 eyi ti wọn pe ni Brazilian Barracoon.

Bakan naa la tun ri kanga ti wọn gbẹ lọdun 1842, eyi ti ẹru meje pere gbẹ, ti wọn n pe ni omi iye, taa mọ si water of life abi Miracle water.

Kanga ọhun si ni wọn gbẹ lati fi ri omi kọ pẹtẹsi akọkọ lorilẹede Naijiria to wa nilu Badagry, ta si tun gbọ pe kanga yii mọ ju ọpọ kanga ti wọn sẹsẹ gbẹ ni Badagry lọ nitori ko ni eroja iyọ ninu gẹgẹ bii awọn yoku.

Kanga miran ta tun foju ri ni kanga to maa n ko ọpọlọ ẹru lọ, ki wọn to tẹkọ leti lọ soke okun.

A gbọ pe awọn ẹrun naa ni awọn oyinbo yoo fun ni omi mu tẹrun, ki ori wọn ma baa pe, lati kọlu wọn loju omi.