Funmi Martins: Sir Shina Peters dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn abiyamọ ayé lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó kú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja olorin Juju, Sir Shina Peters ti dupẹ lọwọ awọn abiyamọ aye fun ifẹ ati itara wọn lori ọrọ ọmọ ti oloogbe oṣere Funmi Martins bi ki o to papoda.

Bakan naa ni Ọgbẹni Peters tun dupẹ lọwọ ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan, Gistloverupdate to gbe ọrọ naa jade.

''Gbogbo ẹyin abiamọ aye ti ẹ da si ọrọ Damilare, mo ki yin fun ifẹ ti ẹ ni si mi,'' Shina Peters sọrọ yii ninu fidio kan to fi sori ayelujara.

Ẹwẹ, iwadii tuntun taa tun ri nipa iku oloogbe Gunmi Martins ree:

Olorin Juju naa sọ pe ''ti eeyan ba mọ inu ro, a mọ ọpẹ da,'' idi niyii ti oun fi dupẹ lọwọ gbogbo awọn to da si ọrọ naa.

Ọgbẹni Peters tun ṣeleri pe oun ko ni ja wọn abiyamọ to da si ọrọ naa kulẹ.

Amọ, Ọgbẹni Peters ko ṣai ṣalaye pe ọrọ pọ ninu iwe kọbọ lori ọrọ naa.

Ṣugbọn akọrin Juju ọhun sọ pe oun o ṣetan lati tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ naa.

Ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára dá Shina Peters lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó kú

Ori ayelujara si n gbona giri giri lori ọrọ gbajugbaja akọrin Juju, Sir Shina Peters ti wọn fẹsun kan pe ko nanii ọmọkunrin kan ti oṣere tiata tẹlẹ to ti di oloogbe bayii Funmi Martins bi fun un.

Ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan, Gistloverupdate lo fọrọ naa soju opo Instagram ati Twitter rẹ.

Gistloverupdate ṣalaye pe olorin Juju Sina Peters ko beere ọmọkunrin yii, Damilare lati igba ti mama rẹ Funmi ti jade laye.

Gistloverupdate tun sọ pe Shina ti pe fun ayẹwo DNA lori ọmọ naa lati mọ daju bo ya oun lo ni ọmọ naa.

Gistliverupdate tun bu ẹnu atẹ lu ọrọ to ni Shina sọ pe kawọn eeyan maa da owo iranwọ fun ọmọ naa mọ.

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo koro oju si ọrọ yii, koda niṣe ni wọn n di ẹbi ọrọ naa ru ọgbẹni Peters.

Abidemi Adumeta SHina Peters kii ṣe ẹni ti eeyan le gbagbọ, o ni kawọn eeyan maa dawo iranwọ lọ fun Damilare.

Dada Margaret sọ ni tẹ pe Sina ko ni ohun kan to fẹ ṣe fun Damilare bii ti wulẹ ko mọ.

Thereallaurel_norman sọ pe ọmọkunrin naa ti di ilumọọka ni, Shina ko ni beere fun ayẹwo DNA.

O ni Shina ko beere fun ayẹwo DNA lori Clarence Peters nitori ọmọ naa ti ṣoriire.

Biola Abiola tiẹ ni ọmọ naa ko nilo ayẹwo DNA kankan tori o jọ Shina ju.

Abiola ni o maa nira fun ọmọkin yii lati dariji Shina Peters ti esi ayẹwo DNA ọhun ba jade.

Princess Ebunoluwa Olujobi woye ni tiẹ pe ohun to mu Shina Peters lati beere fun ayẹwo DNA fun Damilare fihan pe oun ati oloogbe Martins jọ ni ajọṣepọ.

@Akinluvmore ni iwa ainitiju gbaa ni Shina Peters n hu.

O ni o yẹ ki oju gba a ti papaa julọ lẹyin ti wọn fi jẹ oye biṣọọbu tan ni ijọ Kerubu ati Serafu.

Gbajugbaja oṣere tiata, Mide Martins ni awọn mi ti i ẹ n bu wi pe o yẹ ko le tọju ọmọkunrin ti mama bi kẹyin ki o to jade laye.

Wọn ni Eledua ti kẹ Mide de bi pe o yẹ ki o le ṣe iranwọ fun Damilare.