Offa robbery: Àwọn afurasí jẹ́wọ́ pé èèyàn mọ́kànlá làwọn yìnbọn pa

"Èèyàn mọ́kànlá ni a yìnbọn pa níbi ìdigunjalè Offa"

Awọn afurasi adigunjale ti wọn n jẹjọ lori iṣẹlẹ idigunjale ọjọ karun un oṣu kẹrin ọdun 2018 niluu Offa nipinlẹ Kwara ti sọ fún ileẹjọ giga ilu Ilorin pe eeyan mọkanla lawọn yinbọn pa lọjọ náà.

Awọn afurasi ọhun, Ayoade Akinnibosun, Ibikunle Ogunleye, Adeola Abraham, Azeez Salawu ati Niyi Ogundiran lo ti n jẹjọ lori iṣẹlẹ naa.

Fọnran to n ṣafihan ijẹwọ awọn afurasi ọhun ni ileẹjọ kọkọ fihan l'Ọjọru ki igbẹjọ to bẹrẹ.

Gbogbo awọn afurasi naa ayafi ọkan ṣoṣo lara wọn lo sọ pe awọn yinbọn pa eeyan mọkanla ti wọn lẹ oko mọ awọn.

Akinnibosun ṣalaye bi ọlọpaa ti wọn ti da duro lẹnu iṣẹ, Michael Adikwu ti sọ foun nipa idigunjale.

O ni lẹyin ti oun gba si Adikwu to ti di oloogbe bayii lẹnu ni oun naa mu eeyan mẹrin mii wọ iṣẹ ọhún.

O ni oun loun ni ọkọ meji tawọn lo ninu idigunjale ilu Offa.

Akinnibosun ṣalaye pe Gomina ipinlẹ Kwara nigba naa, Abdulfatai Ahmed lo foun lọkan lara awọn ọkọ ọhun gẹgẹ bi ẹbun nitori olori kan loun jẹ lagbo oṣelu nipinlẹ naa.

"Ni ọjọ karun oṣu kẹrin ọdun 2018 ni emi at'awọn mẹrin ti mo mu wọ inu iṣẹ adigunjale gbera lati ilu Oro lọ si Ajase-Ipo nibi ti a gbe ọkọ SUV Lexus ti a wa ninu rẹ sí.

Lati ibẹ ni a ti gbe ọkọ Mercedes Benz lọ si ilu Offa, niwaju ile epo Total ni a duro sí nibi ti Adikwu ti n duro de wa," Akinnibosun ṣalaye.

O ṣalaye siwaju síi pe níbẹ ni Adikwu ti gbe baagi ti ibọn AK47 marun un wa ninu rẹ foun eleyii ti oun fun onikaluku ni tirẹ.

Akinnibosun ni Adikwu ṣọ pe oun wa lati gbẹsan bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe yọ oun niṣẹ, o ni ibọn AK47 mẹwaa lawọn gba lagọ ọlọpaa lasiko idigunjale Offa.

Àmọ́, adajọ Haleemah Salman sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹdogun ati ọjọ kẹrindilogun, oṣu kẹta, ọdun 2021 fun igbẹjọ to kẹyin.