You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lori iro: Evangelist Gbadamosi Ismail, oníwàásù tó di gbajúgbajà ọ̀sán gangan nítorí ìwáàsù apanilẹ́rìn rẹ́
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan ọkunrin kan to n waasu laarin adugbo, ṣugbọn ti iwaasu rẹ jẹ ara meeriri.
Iwaasu naa to jẹ 'apanilẹrin' fun ọpọ eeyan nitori awọn ọrọ ti ọkunrin naa n sọ lo da lori ọrọ ifẹ laarin ọkunrin ati obinrin.
Ninu fidio naa, niṣe ni ọkunrin naa n kigbe tantan pe lori irọ ni ọpọlọpọ adehun ati ọrọ laarin awọn ololufẹ, paapaa bi ayajọ ololufẹ, Valentine, ṣe ku ọjọ diẹ ti yoo waye.
Lati asiko naa si ni ọrọ iwaasu ọkunrin naa ti bi àṣà tuntun, 'lori irọ', eyi ti ọpọ eniyan n da lori ayelujara.
Taa ni ọkunrin oniwaasu to di gbajumọ ọsan gangan?
Orukọ ọkunrin yii ni Ajihinrere Gbadamosi Ismail.
Gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara Instagram rẹ, @evangismail, o sọ pe oun ma n waasu ihinrere pẹlu gbogbo nkan ti oun ni, ti oun si jẹ.
- Ìdí tí mo fi ní ọ́jọ́ ikú ni ọ̀la ọjọ́ Valentine fún àwọn kan - Mike Bamiloye
- Pásítọ̀ Adeboye kéde ààwẹ̀ ọjọ́ 63 fọ́mọ ìjọ rẹ̀, ariwo sọ lórí ayélujára
- Oba Yesufu Asanike I, Olubadan tó fi èèyàn joyè jùlọ̀ láì fi ẹ̀yà ṣe
- Wo ojú àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ níbi ìkọlù NURTW ní Obalende
- Àsìkò tó láti gbé olóògbe Lateef Jakande wọ káà ilẹ̀ sùn
- Ẹnikẹ́ni tó bá dàgboro rú lórúkọ ìwọ́de #EndSARS, aò ní fọwọ́ kékeré mú o - Lai Mohammed
Lẹyin to di gbajumọ lo ṣi oju opo ayelujara Instagram yii ati ti Twitter bakan naa.
O ni inagijẹ oun ni "Baba Lori irọ 1".
Ohun to wọpọ ninu awọn fidio iwaasu ọkunrin naa ni pe pẹlu orin, ijo ati aago lo fi n waasu lọna to pani lẹrin.
Ọrọ irọ pipa laarin ololufẹ si lo jẹ afojusun rẹ ninu awọn fidio iwaasu to wa lori ayelujara rẹ.
O ni "mi o mọ pe iru ọjọ bayii yoo wa, ti gbogbo fidio ti awọn eeyan ma n ya lasiko ti mo n waasu, yoo di ilumọọka, ti yoo si wulo.
"Ọpọ lo n ya fidio naa nitori ki wọn le rẹẹrin, awọn miran lati fi mi ṣe ẹlẹya, ati fun awọn mii lati gbọ otitọ to wa ninu iwaasu mi."
O ni ṣugbọn oun ko bikita fun idi ti wọn fi ya a, to ba ṣa a ti jẹ ọna lati jiṣẹ ti mo ran iwaasu mi."
Oriṣiriṣi awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ lo si ti n fi iwe pe e fun ifọrọwanilẹnuwo lati igba to ti di gbajumọ oniwaasu.
O ṣe apejuwe awọn ifọrswanilẹnuwo naa gẹgẹ bi awọn ilẹkun tuntun, ti oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun.