You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obalende Shooting: Ìkọlù láàrin àjọ NURTW ní agbègbè Obalende dá wàhálà sílẹ̀
A gbọ wipe eeyan mẹfa ni ọwọ ti tẹ to lọwọ ninu iro ibọn yinyin to da gbogbo adugbo Obalende ru ni ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2021.
Ileeṣẹ Ọlọ́paa ipinlẹ Eko ti kawọ iṣẹlẹ naa ko ti ohun gbogbo si ti n lọ deede bo ṣe wa tẹlẹ ni Obalende, ipinlẹ Eko.
Ninu iwadii lati gbọ wipe ikọlu kọgba naa waye laarin awọn ẹgbẹ awakọ agbegbe naa ṣugbọn ko si ẹmi kankan to ṣofo.
Ẹwẹ awọn afurasi ti ọwọ tẹ, wọn ti fi panpẹ ọba mu wọn wọn si ti ko wọn le ọlọpaa lọwọ.
Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP HAkeem Odumosu ti kilọ pe awọn ko ni faaye gba igbesẹ ti ko ba ofin mu rara ni ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe tẹ wa lọwọ, iroyin n gba ori ayelujara kan pe iro ibọn n dun ni agbegbe Obalende ni ipinlẹ Eko.
Lasiko iṣẹlẹ naa, wọn afurasi to n yin ibọn ko ye ẹnikẹni amọ awọn fidio to han kaakiri oju opo ayelura fihan bi awọn eeyan ṣe n sa wọdi wọdi kiri.
- Ọmọ Séríkí Fulani yarí: òfin làwa ń tẹ̀lé, àwọn ará ìlú ò tó láti lé wa kúrò ní Igangan
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ń yí àwọn èèyàn sí oníbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo - Alfa Abbas
- Lẹ́tà mi sí ààrẹ Buhari lóríi àwọn adári tó gba Fulani láàyè ní Nàìjíríà - Oluwo ti Iwo
- 'Sunday Igboho dáná sun àwòrán bàbá wà kódà ó tún yìnbọn sókè nígbà tó wà sí ilé wà ní Eggua'
Awọn eeyan ti bẹrẹ si ni fi ikilọ sita pe "ẹ dakun bi ẹ ba n lọ si Obalende, tabi agbegbe Ikoyi, ẹ pada sẹyin toripe awọn agbero n ja ti ko si tii si agbofinro kankan to yọju.
- Ṣé lóòtọ́ lóòtọ́ ni Femi Fani Kayode ti darapọ̀ mọ́ APC?
- Àìrìjìnà ni àìrábuké ọ̀kẹ́rẹ́, orí ọ̀kadà ni wọ́n ń gbé òku sí lọ mọ́súárì
- Àwọn darandaran tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ wọ ọgbà Soyinka, kí ló tẹ̀yìn rẹ̀ bọ̀?
- Oba Yesufu Asanike I, Olubadan tó fi èèyàn joyè jùlọ̀ láì fi ẹ̀yà ṣe
- Ìròyìn ayọ̀! Tessica tó fi 'glue' lẹ irun pọ̀ tí rí ẹlẹ́yinjú àánú Dókítà tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ orí fún un
Ẹwẹ, ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ọrọ sita lori ayelujara pe "igbakeji ọlọpaa atawọn ikọ wa ti wa nilẹ lati koju iṣẹlẹ naa. Ẹ ṣeun ti ẹ kan si wa".
A n ṣe akojọpọ iroyin lọwọ...