Gorilla glue Girl: Ọmọ Ghana, Dr Michael Obeng rí irun Tessica olórí gúlúù fọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Arabinrin to fi 'Gorilla Glue' lẹ irun ori rẹ ti pada ri ọna abayọ, lẹyin oṣu kan to fi jagun titi ti ko rii ṣe.

Ẹni ogun ọdun naa gbera lati ilu Louisiana lọ si Los Angeles ni Ọjọru, lati ri dokita kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana ati America, Dokita Michael Obeng, fun ọna abayọ.

Laipẹ yii ni Tessica Brown di gbajugbaja lori ayelujara lasiko to fi fidio kan sita nitori iṣoro to n koju.

Diẹ lo ku ko pe oṣu kan nigba naa, to ti ṣeeṣi fi 'gorilla glue' ti wọn fi n lẹ igi, ati awọn nkan mii to l'agbara, lẹ irun rẹ.

Gbogbo igbiyanju rẹ lati fi ọṣẹ ati omi fọ ọ danu lo jasi ofo. Bẹẹni ko ri ọna abayọ nileewosan.

Ṣugbọn ori rẹ gbe e pade alawo ire, nigba ti Dokita Obeng kan si i pe oun yoo ṣe itọju rẹ lọfẹẹ.

Dokita naa ṣe iṣẹ abẹ si irun rẹ, lati yọ 'gorilla glue naa kuro.

Iroyin sọ pe wakati mẹrin ni isẹ abẹ naa fi waye, ati pe bi ẹgbẹrun mejila Dọla ni Tessica i ba san, ka ni dokita naa fẹ ẹ gba owo.

Iru eniyan wo wa ni Dokita Michael Obeng to gba Tenessa ninu iṣoro rẹ?

Wo nkan to yẹ ki o mọ nipa rẹ?

  • Orilẹede Ghana ni wọn ti bi Dokita Obeng
  • Akọṣẹmọṣẹ ni ninu imọ iṣegun iṣẹ abẹ lati tun ara ṣe 'plastic surgery'
  • Ilu Beverly Hills, nipinlẹ California lo n gbe nilẹ America
  • Fasiti Harvard lo ti kẹkọọ. Koda ni ọdun 2011 ati 2014, orukọ rẹ wa lara awọn dokita isẹ abẹ 'plastic surgery' to dara ju ni America
  • Lọwọlọwọ, oṣiṣẹ ileewosan Cedars Sinai Hospital ni, o si ti fi igba kan jẹ Dokita Agba fun isẹ abẹ ṣiṣe nileewosan St. Elizabeth Health Centre
  • Iriri to pọ ni Dokita Obeng ni ninu isẹ abẹ.
  • Oun si ni oludasilẹ Miko Med Spa, to wa ni Beverly Hills.
  • Awọn gbajumọ, ati lọbalọba si ni onibaara rẹ.

Ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ fún Tessica tó fi 'glue' lẹ irun pọ̀ nígbà tó rí ẹlẹ́yinjú àánú Dókítà tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ orí fún un

Ori ti ko ọmọbinrin Jessica Brown yọ o, lẹyin to ri dokita ti yoo ṣe iṣẹ abẹ fun un nitori ''glue' to fi lẹ ori rẹ, ti ko ṣi lẹyin oṣu kan.

Jessica Brown ni ọrọ rẹ gba ori ayelujara kan nitori o lo ''gorilla adhesive glue'' Lai kii ṣe 'hair spray' lati fi lẹ irun rẹ.

Amọ Dokita Micheal Obeng ti wọn bi lorilẹede Ghana, amọ to n ṣiṣẹ ni Amerika, ti ni oun yoo ṣiṣẹ abẹ fun un ni ọfẹ ti irun naa yoo fi ṣi.

Ọmọbinrin naa lo 'glue' hun ki irun rẹ ba le duro si oju kan lati bi oṣu kan sẹyin, ti o si ti sa gbogbo ipa rẹ lati ṣi 'glue' ọhun kuro ni ori, amọ ko ṣi rara lẹyin to ti fọ nigba mẹẹdogun.

'Glue' ti omobinrin yii fi si ori ni won ma fi n le 'tiles' inu ile ati baluwe ati lati ko koi le.

''E gba mi o, iru mi ko kuro ni oju kan o, mo ti fo o bi igba marundinlogun, amo o le pa sibe ni''

Aṃọ, Dokita Obeng ni aanu ọmọbinrin Jessica naa ṣe oun nigba ti oun gbọ iriri rẹ.

Dokita naa ni awon yoo wa ṣe iṣẹ abẹ fun un, ti wọn yoo si kun un lorun ki o ma ba a jẹ irora.

Dokita to jẹ asaraloge naa ni awọn yoo lo 'chemical' lati fi fọ ori naa.

Iru iṣẹ abẹ yii yẹ ko naa ni iye owo ẹgbẹrun mejila dọla owo ilẹ okeere, amọ dokita naa ni ọfẹ ni oun yoo se e fun un.

Ogbontagiri Dokita ni Obeng gege bi a ṣe rika ni oju opo rẹ lori ayelujara, ti o si tun da ileeṣẹ eto ọfẹ ti n kọ awọn eniyan ni iṣẹ abẹ ṣiṣe araloge, ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Restoring Emotional Stability Through Outstanding Reconstructive Efforts (Restore).'

'Ẹ gbé ohùn àdúrà sókè fún mi o! nítorí 'glue' lẹ irun mi pa kò bá ṣí mọ́'

Arabinrin kan to n gbe nilu Louisiana ti deero ileewosan lẹyin to ṣe e ṣi fi eroja ti wọn fi n lẹ nkan pọ "Gorilla Glue spray adhesive' si irun orí rẹ dipo jẹẹli irun.

Ibẹrẹ oṣu Keji ni iroyin ìṣòro to doju kọ Tessica Brown jáde si ori ayelujara.

O sọ ninu iroyin naa pe oun ti n gbe irun ti oun ṣe kiri lati bi oṣu kan, nitori pe oun se àṣìṣe nipa lilo 'glue' ti ko yẹ ki oun lo lasiko ti eyi to ma n lo tán.

O sọ lori ayelujara Instagram pe igba mẹẹdogun ni oun ti fọ irun orí oun, sugbọn eroja naa ko kuro.

"Irun mi ti lẹmọ awọ ori, ko ṣi rara."

Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni itakun agbaye Gorilla Glue, omi ko le ṣi danu, wọn si saba ma n fi lẹ taisi iléèwẹ̀, igi mọ ilẹ inu ile, ati àjà ile.

Eroja acetone tabi isopropyl alcohol lo le ṣí i.

Ileesẹ to n ṣe 'glue' naa si ti ba Arabinrin Brown daro lori Twitter, nigba ti wọn gbọ nkan to ṣẹlẹ si.

Ọjọ Satide ni Brown fi fọto ara rẹ si ori Instagram rẹ @im_d_ollady lasiko to lọ si ileewosan St. Bernard Parish Hospital ni Chalmette, Louisiana, lati ṣi eroja naa danu.

O rọ àwọn eeyan lati ma a gbadura fun lati la wahala yii kọjá, ati pe ki o ma padanu irun rẹ.

Kini ileesẹ Gorilla Glue sọ?

Ileesẹ to n ṣe 'glue ' naa sọ pe àrà ọtọ ni nkan to ṣẹlẹ si Arabinrin Tessica, ati pe eroja to lo kii ṣe fun irun.

Wọn ni "eroja ti a n ṣe kii ṣe fun irun, nitori pe o ma n lẹ nkan pọ titi lai ni. O le gbiyanju lati rẹ irun naa si inu omi to lọwọọrọ, omi ọsẹ tabi ki o fi alcohol pa irun naa.

Titi di asiko yii, Arabinrin Tessica ṣi wa ninu ìṣòro rẹ.

Iroyin TMZ ti ẹ sọ pe o n gbeero lati gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ, nitori pe ohun ti ileesẹ naa sọ pe ko ṣe ko tán ìṣòro rẹ.

Awọn to sunmọ obinrin naa sọ pe wakati mejilelogun lo lo ni ileewosan.

Nise ni eroja acetone ti awọn oṣiṣẹ eto ilera fi si ipakọ rẹ n bo awọ ori rẹ.

O mu ki 'glue' naa rọ, sugbọn ṣe lo tun sare le pada.

Ni bayii, Tessica ti n tọrọ owo fun iwosan rẹ, o si ti ri ẹgbẹrun mẹsan Dọla ($9,000) ko jọ.

Ileesẹ GC sọ pe awọn kọ eewọ si ara gbogbo ọjà wọn, pe iṣẹ titi lai lo ma n ṣe.

"Sugbọn, a gbọ pe Tessica ro pe ko sewu ti oun ba lo o, nitori pe gbogbonise ni."