Ronke Oshodi Oke Yoruba Film: Nígbà tí ǹkan aburú bá ṣẹlẹ̀, àwọn olólùfẹ́ gaan ló máa sọ̀rọ̀ - Ronke Oshodi Oke

Bi awọn ololufẹ gbajugbaja oṣere, Ronke Anthony-Ojo ti gbogbo eeyan mọ si Ronke Oshodi Oke ṣe n faraya lori ayelujara lori pe o padanu lara ọyan rẹ to tobi ti di ranto.

BBC Yoruba kan si ilumọọka oṣere yii lati mọ iha ti oun funrarẹ kọ si ọrọ ti awọn eeyan n sọ lori ayelujara.

''Mo kan "slim down" naa ni o, ko si babara nibẹ, ṣe ẹ mọ wipe nkan ti eeyan fẹ yatọ si nkan ti o n wu ẹlomiran lara eeyan.''

Lootọ awọn eeyan gba pe ko saburu ninu pe o jo lara ṣugbọn ohun to n ka wọn lara ni wipe abusi Edumare nla iyẹn ọyan ti o ni to si n wu awọn ololufẹ rẹ mii ninu ere to tun jo lo n ka wọn lara.

Ronke Oshodi Oke ni "ọra ti pọju ninu ọyan yẹn ni, ati lara. Ṣe ẹ mọ wipe eeyan ti n dagba, awọn nkan mii si wa to yẹ keeyan tete mojuto.''

O ni ''Nigba ti eeyan ba maa fi sunmọ ẹni aadọta ọdun, awọn nkan mii o ni ṣee ko mọ"

Tori naa ni Ronke Oshodi Oke ṣe ni oun yan lati gbe igbesẹ yii. O ni o ti pẹ toun ti fẹ jo lara amọ ti oun n wo wipe haa ṣe oun yoo wa padanu ọyan yii ni.

"O kan jẹ asiko yii ni awọn eeyan ṣẹṣẹ ri i ni. Latinu oṣu kẹfa ni mo ti bẹrẹ ilana jijo lara yii ṣugbọn ẹyin ololuf mi ṣẹṣẹ n ri i ni".

Ṣe jijo lara yii s Ronke di alaisan ni?

Ronke Ojo jẹ ko di mimọ pe fun ilera ara oun ni nkan ti oun ṣe yii. "Nigba ti nkan aburu ba ṣẹlẹ si eeyan tori iru nkan bayii, awọn ololufẹ yẹn gaan lo maa kọkọ sọrọ".

Nigba ti a bi Ronke pe ki ni iyatọ laarin igba ti o ni yan nla ati asiko yii ti ara rẹ ti jo, Ronke ni awọn ara ile lo ro wipe nkan yipada ti wọn n pariwo.

"Ni temi, ko si iyatọ kankan ninu nkan ti mo ṣe nisisiyii. Koda bi mo ba wo ara mi ninu ile, mi o ri i wipe nkankan lọ lara mi. Ọra lasan lo wa nibẹ ti wọn si yọ kuro".

Ronke Oshodi Oke jẹ ko ye BBC Yoruba wipe nkan to ṣe pataki to si wu oun loun ṣe amọ oun ko ṣaisan rara bi awọn kan ṣe n ro.

Iru kọmu wo ni Ronke Ojo n w bayii to yat si igba to ni ọyan nla?

"Ko si iyatọ ninu kọmu ti mo n wọ nisisiyi ati ti tẹlẹ". Ọrọ yii gan ya akọroyin BBC Yoruba lẹnu amọ gẹgẹ bi obinrin, loot o ṣeeṣe ki ibi ara ti eeyan n so okun kọmu mọ ma fibẹẹ yatọ.

"Iyatọ to wa ni wipe 110kg ni gbogbo sisanra mi tẹlẹ amọ nibayii, mo ti di nkan bii 87kg. Mo si nifẹẹ rẹ bẹẹ".

Ki ni imọran Ronke fun awọn ololuf to ka lara pe ọyan rẹ jo?

Ẹbẹ ni Ronkẹ fi bẹẹ pe ki awọn ololufẹ oun to ba binu ma binu si oun rara nitori wipe tori ilera oun loun ṣe ṣe e.

"Ẹ ba mi bẹ awọn ololufẹ mi ki wọn wa nkan mii wo lara mi ju yan yii lọ".

Ronke ni tẹlẹ kii fi bẹẹ ṣe tori ọyan ni awọn akẹgbẹ oun ṣe n pe oun si ere ati awọn ipa ti oun ko nitorinaa ki awọn ololuf oun ma fi tiyẹn ṣe rara.