Unusual foods: Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà

Ounjẹ lọrẹ awọ la mọ ti wọn n wi bẹẹ si ni a ma n sọ pe ohun ti ẹyẹ ba jẹ lẹyẹ n gbe fo.

Ko si ibi ti wọn ki da ina alẹ alẹ sugbọn ọbẹ lo maa n yatọ.

Ni ilẹ Yoruba ati jakejado Naijiria lawọn eeyan ti n jẹ orisirisi ounjẹ.

Se ẹ ri orisirisi taa darukọ yẹn, labẹ rẹ lati fẹ yabara wọ awọn ounjẹ eyi to ri bakan tawọn eeyan a maa jẹ ni Naijriia.

Alaye ri bakan yi ko ju pe awọn eeyan a maa ko ara siọ bi wọn ba gbọ pe iru nkan ta fẹ ka silẹ lawọn ẹlomiran sọ di ounjẹ ti wọn n jẹ.

Diẹ ree lara awọn ounjẹ wọn yi:

Ejo:

O loju eeyan ti ko ni fere ge ti wọn ba sọ pe ejo nbọ.

Amọ ejo tawọn kan n bẹru ti a si maa rin awọn iran lọkan lawọn eeyan Naijriia a maa dinta si sọ di ajẹpọnula.

Bi ẹ ba de ilu kan ti BBC Yoruba sabẹwo si, ẹ o ri ọja ti wọn ti n ta ẹran ejo bi igba ti eeyan n ta ẹran adiẹ.

Adan:

Ko seku ko sẹyẹ, adan ni wọn n pe bẹ.

Bi a se n kọ ọrọ yi gan an a ko mọ boya ki a pe e ni ẹye tabi ẹranko sugbọn fun anfaani ọrọ ti a n ba bọ, awọn eeyan kan a maa jẹ adan ni Naijiria yi kan ti a wa.

Bi eeyan ba n rin irinajo to gba oju ọna marose kọja lawọn ilu tabi ileto kan yoo ri ti wọn gbe adan kọ ti wọn ta bi ẹran igbe.

Lawọn ọja lekulẹja mii adan a maa wa lori igba bo ti lẹ jẹ wipe asejẹ ni wọn fi iru adan wọn yi jẹ.

Se ẹ fẹ mọ orisi nkan ti wọn n ta lọja lekulẹja?

Aja:

Ounjẹ eleyi jẹ eyi tawọn ipinlẹ kan ni Naijria kii se sere bo ti ẹ se wi pe gbogbo eeyan kọ ni o maa n jẹ.

Se ẹ ti gbọ nipa ''looki''?

Eran aja lo n jẹ bẹ ni awọn apa kan ipinlẹ bi Ondo ti wọn ti n jẹ.

Awọn eeyan a tun maa jẹ aja ni Akwa-Ibom, ipinlẹ Cross Rivers ati Eko.

A gbọ pe wọn a tun maa pe aja ni ''404'' to si jẹ pe ẹmu ati epo pupa lawọn kan a maa fi jẹ aja.

Bi ẹ ba de orileede China, wọn a maa jẹ aja nibẹ koda ọja wa ti wọn ti n ta aja.

Amọ ijọba ibẹ ati awọn ajafẹtọ ẹranko n tako iru isesi ki eeyan maa jẹ aja yi

Ọpọlọ maalu:

Kwanya lorukọ tawọn ẹya to n jẹ iru ounjẹ yi n pe ni Naijiria.

Kaka ki ẹ ba bọkọtọ, saki tabi panla ninu omi ọbẹ, awọn ẹya Naijiria kan fẹrna ki wọn maa fi ọpọlọ maalu, ẹran tabi ti aguntan se ọbẹ.

Bi eeyan ko ba ba lọkan daada o le ma le bawọn jẹ iru ounjẹ yi sugbọn lọdọ awọn to fẹran rẹ ni jijẹ ọbẹ aladun ni!

A tun gbọ pe awọn eeyan India naa fẹran jijẹ ọpọlọ maalu tabi ti ẹran.

Esunsun:

Lasiko ti ojo ba sẹsẹ rọ tan lawọn esunsun ma n jade sita.

Bi awọn eeyan ba ti ri wọn paapa awọn ọmọde, wọn a gbe ike sabẹ ina mọnamọna lati mu wọn.

Kokoro lawọn kan le foju ka awọn esunsun sugbọn lọdọ awọn to kundun wọn ni jijẹ, ounjẹ aladun ni wọn jẹ.

Ni ilẹ Yoruba ati awọn ibomiran ni Naijira lawọn eeyan ti n jẹ esunsun ti wọn a si ta aya wọn sina.