What is Valentine?: Ẹ wo bí àwọn gbajúmọ̀, òṣèré ṣe ṣe àyájọ́ Ọjọ́ Valentine

Ibeere nla yii ni Mercy Aigbe beere loju opo ayelujara.

Gbajugbaja osere Yoruba naa ni Ṣé ìyàwó ilé tàbí àlè níta ló yé kí ọkùnrin lo 'Valentine' rẹ̀ pẹ̀lú?

Idahun si ibeere yii si ṣotọọtọ loju opo ayelujara lati ana to ti beere rẹ

Bi awọn kan ṣe n sọ pe iyawo to wa ninu ile lo yẹ ki eeyan ba sami ayajọ ololufẹ naa ni awọn miran n sọ pe ale ni ita lo maa gbadun ju.

Ọpọlọpọ awọn ololufẹ lo ma n farahan lati ṣe ayajọ Ọjọ Ololufẹ, Valentine's day ti wọn yoo si fi ifẹ han si ara wọn.

Aṣọ pupa si ni ọpọlọpọ eniyan ma n wọ ni ọjọ naa lati fi ifẹ han si ara wọn.

Awọn gbajumọ lawujọ to fi mọ awọn oṣere ko gbẹyin nibẹ lọdun yii lati fi ifẹ han si ara wọn, pẹlu asọ alaranbara ti wọn fi ṣe ara wọn lọsọ.

Ẹ wo aworan awọn gbajugbaja ti wọn fi si oju opo Instagram wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ayajọ ọjọ ọlọlufẹ ti ọdun yii.

Ẹ wo bí àwọn gbajúmọ̀, òṣèré ṣe ṣe àyájọ́ Ọjọ́ Valentine

Wo àwọn ọ̀rọ̀, ewì, àwòrán tí kìí ṣe 'lórí irọ́' tí o lè fi yẹ́ olólùfẹ́ rẹ sí fún Valentine

Ayajọ ololufẹ miran tun wọle de wẹrẹ.

Ọsẹ ifẹ ni ọsẹ ayajọ ololufẹ jẹ ti o si maa n kun fun ọpọlọpọ idunu ati ireti fun awọn eeyan.

Oniruuru eto lawọn eeyan ti maa n la kalẹ fun paripari ọsẹ naa to jẹ ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2021.

Amọṣa oniruuru ọna ati anfani lo wa lati fi ifẹ han fun ololufẹ rẹ.

Sise akanṣe ounjẹ, fifi asiko silẹ lati ba ololufẹ ẹni ṣere pọ, akanṣe apejẹ tabi ipagọ, ẹbun ati bẹẹbẹẹlọ kun ara rẹ.

Eyi ni diẹ lara awọn ọrọ ikini ati atẹjiṣẹ, aworan ati bẹẹ bẹẹ lọ ti o lee fi mu inu ololufẹ rẹ dun ni ayajọ ololufẹ.

"Mo ni ifẹ rẹ loni, lọla ati titi aye, ṣugbọn mo fẹ fi ifẹ pupọ sii han fun ọ lọjọ ti oni yii. A ku ajọyọ ayajọ Valentine ololufẹ mii."

"Oni ni ọjọ ti a ya sọtọ fun wa lati gbadun ara wa ki a si ni ifẹ ara wa. Mo fẹ ṣe ayajọ Valentine yii ni ara ọtọ gẹgẹ bi iwọ pẹlu ṣe jẹ ara ọtọ fun mi. A ku ajọyọ ayajọ Valentine ololufẹ mii."

" Iwọ ni ala mi to dun julọ, igba ti o ko ba si si pẹlu mi lo maa n jasi igba ẹru to le juls fun mi. N ko lee duro lati tun fi oju kan ọ ololufẹ mi. A ku ajọyọ ayajọ Valentine ololufẹ mii."

" Iwọ ni afojusun kan ṣoṣo ti mo ni laye. Mo fẹ nifẹ rẹ, mo fẹ tun nifẹ rẹ sii ni gbogbo ọjọ. A ku ajọyọ ayajọ Valentine ololufẹ mii."

Ki ni pataki ayajọ Valentine gan naa?

Oniruuru itan lo ti bi ayajọ Valentine ṣe ṣẹ wa lẹyin . diẹ lara rẹ niwọnyii.

Gẹgẹ bi iwe aṣeranwọ lori itan akọsilẹ, Britannica ṣe sọ, ninu ọdun ilẹ Romu kan ti wọn n pe ni ajọdun Lupercalia, eyi ti wọn maa n ṣe ni aarin oṣu keji ọdun ni ayajọ Valentine ti ṣẹ jade wa.

Lasiko ajọdun naa, wọn maa n so obinrin ati ọkunrin pọ nipasẹ tẹtẹ oriire kan ti wọn maa n ṣe. Igbagbọ ọpọ ni pe Poopu Gelasius kinni lo yi ajọdun naa pada si ayajọ Valentine ki o to di bii ọdun pupọ sẹyin ti wọn wa bẹrẹ si ni n ṣe ajọyọ ifẹ lọjọ naa.

Bawo ni Itan Valentine ṣe bẹrẹ?

Awọn itan miran tilẹ tun sọ pe o da lori eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Valentine.

Awọn kan tilẹ ni wọn fi ọjọ naa sọ orukọ St. Valentine ti Terni to jẹ Biṣọbu.

Itan miran dẹ tun sọ wi pe ọjọ naa gba orukọ rẹ lati ara alufa kan to n jẹ Valentine, ẹni ti wọn ni o figbakan ri fi lẹta ranṣẹ si ọmọbinrin wọda ẹwọn to wa to si pe akori lẹta naa ni "from your Valentine" to tumọ si, "lati ọdọ Valentine rẹ."

Lọdun 270 CE ni olori ilu Romu Emperor Claudius II Gothicus pa nitori ẹsin rẹ.

O ṣeeṣe ki awọn mejeeji yii jẹ ọkan naa, gẹgẹ bi iwe Britannica ṣe sọ.

Awọn aworan to dunlẹ ti ẹ le lo fun ololufẹ yin lasiko Valentine yii ree.