Shasha violence in Ibadan: Kíni àwọn gómínà láti Àríwá Naijiria sọ lórí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Shasha?

Awọn gomina lati ariwa orilẹede Naijiria ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn pẹlu ija ẹlẹyamẹya to waye ni ọja Shasha ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Eyi ko ṣẹyin ayẹwo ti wọn ti ṣe si gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lẹyin ija ẹlẹyamẹya to waye ni ọja Shasha ni ilu Ibadan.

Awọn gomina naa lati ariwa Naijiria ni gomina ipinlẹ Niger,Abubakar Sanni Bello, gomina ipinlẹ Zamfara ,Bello Mohammed Matawalle, gomina ipinlẹ Kano, Abdulahi Umar Ganduje ati gomina ipinlẹ Kebbi,Abubakar Atiku Bagudu.

Awọn gomina naa ṣe ipade pẹlu Seyi Makinde ni ile ijọba ni agbegbe Agodi, ni ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Ẹmi eniyan kan lọ si iṣẹlẹ naa nibi ti ariyanjiyan ti waye laarin Hausa ati Yoruba, ti ọpọlọpọ dukia si lọ si ikọlu naa.

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni oun yoo ri wi pe alaafia jọba nipinlẹ Oyo, ti awọn a si ri wi pe awọn to wuwa ọdaran naa fi oju wina ofin.

É dẹ́kun ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Shasha, èyí kò sí nínú àṣà ìran Yorùbá- Akeredolu

Leyin ikọlu to waye ni agbegbe Shasha ni ilu Ibadan ni Gomina Rotimi Akeredolu to jẹ alaga awọn gomina ni ipinlẹ ẹkun Iwọ oorun guusu Naijiria ti bẹ awọn ara ilu.

Akeredolu parọwa pe ki onikaluku jogun o sinmi lasiko yii.

O ni ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ ati pe ki awọn eeyan ma jijangbara tẹ oju ofin mọlẹ nitori ohun to n ṣẹlẹ.

O parọwa fawọn eeyna pe iṣoro eto aabo yii a dopin laipẹ ni Naijiria ti onikaluku ba fi suuru ṣe.

Akeredolu ni ọrọ eto aabo yii ti n beere fun apero ọmọ eriwo gbogbo iran Yoruba ati awọn ẹya to ku ni Naijriia.

Gomina ipinlẹ Ondo ni pataki ti amọ iran Yoruba mọ ni pe ifarada, suuru ati iwa akin lasiko to ba yẹ lati gbe igbesẹ to yẹ.

O ni yiyọ ẹkun kii ṣe nipasẹ ti ojo rara lasiko yii ṣugbọn ọrọ naa gba ero ṣaaju awọn igbesẹ akin to yẹ.

Gomina ipinlẹ Ondo lasiko to n sọrọ nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni agbegeb Shasha ni ilu Ibadan lopin ọsẹ yii ni o ba ninujẹ gidi.

O ni oun mọ pe Gomina Seyi Makinde to n tukọ ipinlẹ Oyo n gbe igbesẹ to yẹ.

O ni atilẹyin lo ku fun gomina Makinde lati bori iṣoro yii pẹlu awọn to ku.