You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Hate Valentine's gift day: Wo ǹkan márùn ún tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fẹ́ ní 'Valentine' 2022
Se lootọ ni pe awọn kan korira ọjọ ayajọ ololufẹ 'Valentine'nitori ẹbun ti wọn n gba?
Awọn ololufẹ kan ni wọn bọ si oju opo ayelujara ti wọn si n sọrọ nipa awọn ẹbun ti awọn ololufẹ maa n fun eeyan ṣugbọn to maa n bi eeyha ninu ni eyi ti wọn n sọ pẹlu #Hate Valentine gift.
Ọpọ lo sọ nipa ododo pe kini awọn fẹ fi ṣe bii Rose, Petal, Tulip, Daisy, Dandelion, Daffodi, Lily, Orchid ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣe lasiko ọgbẹlẹ ni Naijiria lasiko yii?
- Aṣọ ń pe aṣọ ráńṣẹ́ láàrin àwọn òṣèré tíátà ní àyájọ́ olúlùfẹ́
- Ìdí tí mo fi ní ọ́jọ́ ikú ni ọ̀la ọjọ́ Valentine fún àwọn kan - Mike Bamiloye
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa ọlọ́pàá ní Enugu, kọlu àgọ ọlọ́pàá ní Anambra
- Wo nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa gbajúmọ̀ oníwàásù 'Lórí irọ́'
- Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọ̀dàn
- "Ẹ̀yin obìnrin, ẹ fi òdòdó ṣe ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́ fún ọkùnrin dípò kẹ gbà kó já òdòdó ara yín"
Iwadii fihan pe awọn eeyan orilẹ-ede Australia gẹgẹ bii apẹrẹ n na to $1.1 bilionu owo dọla lọjọ ayajọ awọn ololufẹ.
Bẹẹ, naa ni wọn ni gbogbo agbaye lo maa n mọ ayajọ ololufẹ yatọ ti ọpọ si maa n na owo to pọ fi ra nkan fun awọn ololufẹ wọn
Ọpọ awọn eeyan yari pe awọn ko fẹ ododo, awọtẹlẹ ọkunrin ti ọpọ mọ si 'Boxer', ati 'Singlet' awọn miran tilẹ ni awọn ko fẹ candle tabi ina alẹ to n mu irin ajo ifẹ dani.
Koda, awọn eeyan miran sọrọ lori awọn ẹbun miran ti ko wulo fun awọn gẹgẹ bii obinrin ni eyi ti awọn ọkunrin miran maa n fun awọn.
Wo diẹ lara awọn ẹbun ti o le fun ololufẹ rẹ to le mu inu rẹ dun loni ayajọ ọjọ Ololufẹ:
1) Ounjẹ aladun ti ko wọpọ:
O le fun ololufẹ rẹ ni ounjẹ ti ko ki n jẹ lojooojumọ nitoti pe o wọn tabi ko wọpọ ladugbo yin
Ololufẹ rẹ yoo gbadun ki wọn gbe " Surprise Dinner' to dun pupọ wa ka a mọ ile.
2) Gbe ololufẹ rẹ lọ ṣabẹwo pada si ibi ti ẹ ti pade nibẹrẹ.
Nkan miran ti ololufẹ rẹ le mu inu rẹ dun si ni ki ẹ jọ pada lọ ṣabẹwo si ibi ti ẹ ti dẹnu ifẹ kọ ara yin ni ibẹrẹ.
Tabi ki ẹ jọ pada lọ si ibi ti ẹ ti kọkọ pade ninu irinajo ifẹ yin.
3) Gbe Ololufẹ rẹ lọ wo sinima to dun mọ ọ ninu julọ.
Iwadii fihan pe ti o ba gbe ololufẹ rẹ lọ wo ere sinima tabi lọ sibi igbafẹ to wuu yoo jẹ ki inu rẹ dun.
Ọpọ lori ayelujara lo n mẹnuba awọn sinima ti o wu awọn lati wo lasiko yii ni eyi ti inu wọn yoo dun ti ololufẹ won ba gbe wọn lo wo.
Koda, awọn kan ni pe ki awọn jọ ka papọ si ori aga pẹlu ifẹ ki awọn jọ tun sinima tabi fimu to dun ti awọn wo ni ibẹrẹ irinajo ife awọn gan an ti to ni oni.
- Wo àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn tètè ní irun funfun lórí láì tíì di arúgbó
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ń yí àwọn èèyàn sí oníbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo - Alfa Abbas
- Olubadan tuntun yóò di mímọ̀ lọ́jọ́ Ajé - Gómìnà Makinde
- Tó bá jẹ́ pé à ń gbé AK47, ìgbà táwọn àgbẹ̀ dáná sun ilé wa, ṣé aò ti ní pa wọ́n dànù? -Ọmọ Seriki Fulani
4) Lo asiko to peye pẹlu ololufẹ rẹ nikan
Ọpọ lo ni ohun ti yoo jọ awọn loju julọ ni pe ki ololufẹ awọn ba awọn lko asiko to peye papọ.
Wọn ni aini asiko to kun fun ọrọ ifẹ ati ihuwasi ifẹ lo n fiya j'ẹ awọn.
Koda, ko ṣe pe ki awọn kan jọ maa sọrọ ifẹ si ara wọn gege bi awọn ṣe jọ se ni ibẹrẹ lasan ti to awọn.