Women, Pregnancy complications: Wo oríṣìí àrùn méjọ to máa ń ṣáábà mú aláboyún

Oríṣìí àrùn mẹ́jọ tó máa ń ṣáábà mú aláboyún rèéAdura gbogbo obinrin to ba ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo naa ni pe ki wọn fi inu ṣoyun fẹyin gbọmọ pọn.

Ṣugbọn ọpọ ni ko mọ awọn irora to wa ninu ipo oloyun.

Dokita onimọ nipa obinrin ati ọmọde, Dokita Joseph Ayinde ṣalaye pe o ṣe pataki ki awọn eeyan mọ nipa awọn arun ọhun.

Wọnyii ni awọn arun oriṣii mẹjọ to máa n ṣaaba ṣe alaboyun:

1. Àrùn iba:

Dokita Ayinde ni arun iba jẹ ọkan lara arun to maa n ṣaaba ṣe awọn alaboyun.

O ṣọ pe awọn ti oyun wọn ko tii ju bi oṣu mẹta lọ ní arun maa yọ lẹnu.

O rọ awọn alaboyun lati maa sun ninu nẹẹti ki ẹfọn maa le jẹ wọn eyi to maa n fa iba.

2. Arun Anemia:

Dokita Ayinde ni arun yii naa wọ pọ pẹlu awọn oloyun.

Ohun ti arun yii tumọ si ni pe awọn alaboyun maa n ni ẹjẹ ruru nitori wọn nilo ẹjẹ to pọ pẹlu bi wọn ti sanra.

Ọna abayọ ni kí alaboyun jẹ ounjẹ to dara ko sí tun lo awọn rẹ bi folic acid deedee.

3. Ẹjẹ ruru:

Dokita Ayinde ṣalaye pe ọpọ oloyun lo maa n ni arun ẹjẹ ruru nitori awọn ati ọmọ to wa ninu wọn lo jọ n pin ẹjẹ lo.

Amọ, dokita naa ṣalaye pe awọn obinrin to ba ti to ọdun mẹrindinlọgbọn lọ soke ni wọn máa n ṣaaba larun yii.

Ọna abayọ ni ṣiṣe ayẹwo nigba gbogbo lati mọ boya ifunpa lọ soke.

4. Arun itọ ṣuga:

Dokita Ayinde ni ipo oloyun le fa arun itọ ṣuga .

Bakan naa ni dokita ọhun tun sọ pe oloyun le jogun arun itọ ṣuga lati ọdọ awọn obi rẹ.

Itọ atọju, eebi ati aigbọran daadaa lawọn àpẹẹrẹ tawọn oloyun to ba larun naa maa n ri.

Dokita ni ọna abayọ ni pe ki alaboyun maa ri dokita rẹ deedee fun itọju to peye.

5. Arun arunmọleegun

Dokita Ayinde ni arun arunmọleegun maa yọ ọpọ oloyun lẹnu.

O ni lilo oogun folic acid lọna abayọ, bi bẹẹ kọ, arun yii le gbẹmi alaboyun.

6. Arun ọkan

Awọn oloyun tun maa n larun ọkan.

Dokita Ayinde sọ pe ipo oloyun tun maa n jẹ ki eeyan ni arun ọkan.

Isinmi lẹnu iṣẹ, riri dokita deedee ati yiyẹ ifunpa wo lọna abayọ.

7. Arun varicose ori iṣan:

Dokita Ayinde ni irufẹ arun ori iṣan yii ko ṣaaba wọ pọ laarin awọn aboyun.

Dokita ni oloyun le dena arun yii nipa sisun silẹ ati nina ẹsẹ soke.

8. Ẹsẹ wiwu ati eebi:

Dokita Ayinde sọ pe ẹsẹ ọpọ oloyun maa n wu, bakan naa lawọn oloyun mii tun maa n ṣaaba bi.

Ṣugbọn Ayinde ni eyi kii ṣaaba ṣakoba fun wọn.

Lakotan, Dokita onimọ nipa awọn obinrin ati ọmọde ṣọ pe o dara ki obinrin bimọ ni ọjọ ori ti ko ju ọdun marundinlogoji lọ tori awọn arun to maa n ṣe oloyun niiṣe pẹlu ọjọ ori wọn.