Pregnancy sleep tips: Wo ìgbésẹ̀ mẹ́wàá fún aláboyún láti rí oorun ṣùn lálẹ́

Oorun sisun kii ṣaba rọrun fun alaboyun, paapaa ni oru, nitori bi oyun ṣe n dagba si, ni ikun rẹ n tobi si, bẹẹ naa ni ọmọ to wa ninu rẹ yoo ma ju apa, ju ẹsẹ.

Niṣe ni yoo si dabi ẹni pe niṣẹju-iṣẹju ni alaboyun naa yoo ma a tọ.

Eyi si jẹ ara awọn nkan to ma n mu ki asiko ti alaboyun fi n sun ni oru dinku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko wọpọ lati ri aboyun ti yoo sun orun asunwọra laarin oru, eyi to mu ki ọpọ eeyan gbagbọ pe ara ọna ti iṣẹda eeyan fi n mura ìyá silẹ fun itọju ọmọ tuntun ni.

Wo awọn nkan ti o le ṣe lati mu ki o ri oorun to dara sun ni oru, ati fun isinmi ti ara rẹ n fẹ ni ọsan.

Omi mimu

Nkan akọkọ ni pe ki o mu omi daadaa ni ọsan, ṣugbọn to ba ti n sun mọ asiko ti o fẹ ẹ sun, din omi tabi nkan olomi ku. Eyi yoo mu adinku ba iye igba ti o ji dide tọ ni oru.

Ma joko tabi duro si oju kan

Lootọ ni ere idaraya yoo nira fun ọ ni asiko yii, sugbọn gbiyanju lati ṣe diẹ.

O le jẹ ki o kan ma a rin kiri inu ile, lati mu ki ẹjẹ ṣan kaakiri ara rẹ, ati din ẹsẹ riro ku laarin oru.

Fi opin si ere idaraya ti o ba fẹ ẹ ṣe, o kere tan wakati meji ṣaaju asiko ti o fẹ ẹ sun.

Ma ṣe gbe ohunkohun si ọkan tabi ronu lasiko ti o ba fẹ ẹ sun

Wahala ati ipaya jẹ gbajumọ lara awọn nkan ti kii jẹ ki eeyan ri oorun sun daadaa ni alẹ.

Ranti pe ironu tabi ipaya ko le ṣe ọ ni oore kankan.

Ti ohunkohun ba n ja ọ laya tabi ba ọ lọkan jẹ, jiroro pẹlu ọkọ tabi ọrẹ rẹ timọtimọ, to le mu ki ọkan rẹ ko fuyẹ.

Ọpọ ironu ti alaboyun ma n ni nipa irọbi, ibimọ, itọju ọmọ tuntun, ati bi igbeaye yoo sẹ ri lẹyin ti ọmọ naa ba de tan, lo ma n fa airoorun sun.

Yi asiko ti o n sun pada

Ti o ba le yan asiko kan naa lati ma a sun ni alaalẹ, yoo ran ọ lọwọ lati sinmi, ki o si sun pẹlu irọrun.

Ti asiko oorun ba ti n to, gbiyanju lati se diẹ lara awọn nkan to le fun ọ ni itura bi i:

  • Mu tii ti ko ni caffeine ninu tabi miliki to lọ wọọrọ pẹlu oyin
  • Jẹ ipanu diẹ bi i bisikiiti kraka tabi ounjẹ onihoro 'cereal'. Awọn ounjẹ yii ni eroja to ma n mu ki oorun tete wa.
  • Ka iwe kan ti o ba dun
  • Wẹ pẹlu omi to lọwọọrọ
  • Tabi ki wọn o ba ọ fi nkan wọ ejika rẹ.

Ma a fi irọri si abẹ ẹsẹ rẹ

Ti oyun ba ti pe ogun ọsẹ, awọn dokita ma n sọ pe ki alaboyun o ma a fi ẹgbẹ osi sun, ki ẹjẹ le ṣan daadaa si ile ọmọ ati kidinrin rẹ.

Gbiyanju lati fi irọri si abẹ orunkun rẹ, ati irọri miran si abẹ ikun.

O si le ma a lo akanṣe irọri fun alaboyun.

Bakan naa ni o le fi irọri yi gbogbo ara rẹ ka ati si ẹsẹ rẹ.

Kapa aya tita

Lati dena aya tita, ma fi ẹyin le lẹ laarin wakati kan si meji ti o ba jẹun tan.

To ba jẹ iṣoro aya tita ni ko jẹ ki o ri oorun sun, fi irọri gbe ori rẹ soke.

Bakan naa ni ki o yago fun ounjẹ to ni ata pupọ tabi eyi ti wọn din.

Awọn ounjẹ bẹ ẹ yoo mu ki aya tita naa buru si.

Sun oorun ọsan

To ba nira fun ọ lati sun daadaa ni oru, gbiyanju lati sun diẹ ni ọsan.

Eyi yoo mu adinku ba rirẹ to le rẹ ọ.

O le sun fun bi ogun tabi ọgbọn iṣẹju ni ọsan tabi lẹyin iṣẹ oojọ rẹ.

Ma jẹ ki o kọja iṣẹju yii, nitori pe oorun asunju yoo tun mu ki o rẹ ọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Ma a ṣe akọsilẹ ounjẹ ti ko ba ọ lara mu

Ti o ba ṣakiyesi pe ọmọ inu rẹ ma n ṣerepa lẹyin ti o ba jẹ ounjẹ to ni ṣuga tabi to ni ata pupọ, ma jẹ wọn fun ounjẹ alẹ.

Bi bẹẹ kọ, ijo alarinrin ni ọmọ rẹ yoo fi gba oorun loju rẹ ni oru.

Jẹ ounjẹ aṣaraloore fun anfaani iwọ ati ọmọ inu rẹ.

To ba jẹ nitori eebi lo ṣe n jẹ awọn ọunjẹ to ni ata ju, o le gbiyanju lati jẹ ipanu 'crackers' tabi awọn mii ti ko dun ju.

Ma a gba atẹgun daadaa

Oyun yoo mu ki ara rẹ ma a gbona ju ti tẹlẹ lọ. Nitori naa lo ṣe ṣe pataki fun ọ lati sun si ibi ti afẹfẹ ba ti n fẹ.

Gbadun asiko naa

Wo o, ti gbogbo nkan ti a ka silẹ yii ba fori ṣanpọn, gba kadara pe nkan ayọ ni.

Ti o ko ba ri oorun sun l'oru, o le rọra maa fi ọwọ pa ikun rẹ, ki o si ma a kọrin aladun fun ọmọ naa.

Ọmọ naa le gbọ nkan ti o ba n sọ bayii.

Boya ti o ba n kọ orin to le mu ki oorun kun, o ṣe e ṣe ki iwọ naa gba ibẹ sun lọ.

Eyi si tun jẹ ọna lati mu ki ọmọ rẹ da ohun rẹ mọ.