You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dr Frabz: Wọ ohun tí a mọ̀ nípa gbajúgbajù olórin ọmọ Naijiria, Dr Frabz tí wọ́n yìnbọn pa ?
Gbajugbaja olorin takasufe, Ayorinde Faboro ti gbogbo eniyan mọ si Dr. Frabz ti doloogbe.
Eyi ko ṣẹyin iroyin to n ja lori ayelujara wi pe wọn yinbọn pa a ni lorilẹ-ede Amẹrika nibi ti oun gbe.
Gẹgẹ bi iroyin ti gbajugbaja olorin, Nikki Laoye fi si oju opo Twitter, o ni niiṣe ni wọn yinbọn pa a.
- Isinkan-Akure regent: Mo pa màálù, àgùtàn àti àwọn ètùtù míì kí ń tó di Adelé Oba ní Isinkan- Adelé Florence Aladetoyinbo
- Àwọn jàndùkú ajínigbé fẹ́ẹ̀ lù wá pa nínú igbó, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ìlú Kagara
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa Dawisu tí gómínà Kano yọ ní íṣẹ́ nítorí o sọ̀rọ̀ tako Ààrẹ Buhari
- Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
Iroyin buruku leleyii o pe eniyan mi, Dr Frabz @DoktaFrabz, ti do loogbe... wọn yinbọn pa, talo ṣe eleyii? o dun mi gidigidi. iru iroyin wo leleyii?
Bakan naa ni akẹgbẹ rẹ olorin, Samklef ni '' erin nla lọ, ayo, a sọrọ ni sẹ meji ṣẹyin to n bere alaafia mi, mo wa si Maryland lana, mo si gbọ wi pe o ko si laye mọ... ọjọ ibanujẹ leleyii! o di gbere!RIP!
Lara awọn gbajugbaja olorin to ti fi ikẹdun wọn si ori ayelujara ni Davido, Samklef ati bẹẹ lọ.
Tani Ayorinde Faboro, Dr Frabz @DoktaFrabz to doloogbe?
- Ipinlẹ Ekiti ni wọn ti bi Ayorinde Faboro, Dr Frabz, amọ ilu Maryland, lorilẹede Amẹrika ni oun gbe ki o to di oloogbe ni ọdọmọde,
- Ọdun mẹfa ni Ayorinde Faboro wa to ti bẹrẹ si ni kọ orin to si n ta duru,
- Ọdun 2006 ni o bẹrẹ orin takasufe gẹgẹ bi i iṣẹ orin kikọ,
- Inagijẹ orukọ rẹ, Dr. Frabz duro fun Doctor of Flavour, Rhythm and Blues,
- Ayorinde Faboro ni oludasilẹ ileeṣẹ to n gbe orin jade, ti o pe orukọ rẹ ni N'sayne Entertainment,
- Bakan naa ni o ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ pẹlu awọn gbajugbaja orin bii Naeto C, Davido, Dagrin, YQ, Shank, Omawumi ati bẹẹ bẹẹ lọ,
- Lara awọn awo orin to gbe jade ni iwalaye rẹ ni orin Dagrin "Thank God", ati orin WizKid' "Bombay", ati "Joy".