You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọdẹ àtàwọn ajínigbé rọ òjò ìbọn fúnra wọn ní Akunnu-Akoko, ẹ̀mi ajínigbé kan sọnù
Ajinigbe kan ti dero ọrun lẹyin ti awọn ẹmẹwa rẹ atawọn ọdẹ ilu Akunnu-Akoko doju ibọn kọ ara wọn ni ijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, nipinlẹ Ondo.
Iroyin ni eeyan meje to n rinrinajo lọ si oke ọya ni awọn ajinigbe ọhun ji gbe lọ lasiko iṣẹlẹ naa.
Ni kete ti iroyin iṣẹlẹ naa tẹ Adele Ọba Akunnu, Ọmọba Tolani Orogun leti, lẹsẹ kan naa ni oun pẹlu awọn ọdẹ ilu atawọn akikanju miran wọ inu igbo lọ tẹle awọn ajinigbe ọhun.
- Ẹ wo àwòrán bí Sunday Igboho ṣe ṣàbẹ̀wò sí Aarẹ Gani Adams nílé rẹ̀ nílùú Eko
- Wọ ohun tí a mọ̀ nípa gbajúgbajù olórin ọmọ Naijiria, Dr Frabz tí wọ́n yìnbọn pa ?
- Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tó tó 4 milionu yóò bàlẹ̀ sí Nàìjíríà
- Sunday Igboho gbọdọ̀ gbàṣẹ ìdáàbòbò láti iléẹjọ́ tí kò ní jẹ́ kí ọlọ́páá mú un- Amòfin Ozekhome
Igbesẹ naa so eso rere lẹyin ti wọn pa ọkan lara awọn ajiigbe ọhun, ṣugbọn awọn akẹgbẹ rẹ na papa bora.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn akinkanju naa doola ẹmi awọn eeyan meje ti awọn ajinigbe naa ti kọkọ gbe lọ.
Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, Adele Orogun ṣalaye pe akitiyan awọn ọdẹ naa so eso rere nitori wọn mọ agbegbe ọhun daadaa.
O ni "awọn ọde wọ inu igbo lọ, wọn si doola ẹmi awọn eeyan meje ti wọn ti ji gbe ṣaaju."
Lẹyin naa lo kan sara si awọn eeyan fun iṣẹ akin ti wọn ṣe.
Ọga ọlọpaa to n ṣakoso agbegbe Ikare Akoko, ACP Razak Rauf ṣalaye pe lootọ ni wọn doola awọn meje ti ajinigbe ti kọkọ gbe lọ, awọn eeyan naa ko si ṣẹṣe rara.
Razak ni wọn ti gbe oku ajinigbe to ba iṣẹlẹ naa lọ si ile igbokupamọsi.
- Fáàbàdà! Ìjọba mi kọ́ ní yóò buwọ́lu ìgbéyàwó akọ sákọ àti abo sábo- Ààrẹ Ghana yarí
- Àwọn jàndùkú ajínigbé fẹ́ẹ̀ lù wá pa nínú igbó, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ìlú Kagara
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa Dawisu tí gómínà Kano yọ ní íṣẹ́ nítorí o sọ̀rọ̀ tako Ààrẹ Buhari
- Mi ò gba kobo ní gbogbo ọ́dún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Osun - Aregbesola
Alagba kan lagbegbe ọhun, Ade Aboginije ke si ijọba ipinlẹ Ondo lati ṣafinkun iye ẹṣọ alabo to wa lagbegbe naa, paapaa ilu Akunnu to sunmọ ala ipinlẹ Edo ati Kogi.
Iroyin ni pupọ awọn agbẹ agbegbe ọhun lo ti fi oko wọn silẹ nitori bi awọn ọdaran daradaran ṣe maa n ji wọn gbe, ti wọn a si maa fi ipa ba iyawo atawọn ọmọ wọn lopọ.
- Èèyàn 341 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tún lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
- Wọ́n ní ọkọ̀ bàálù NAF tó mú ẹ̀mí ọmọ mi lọ l'Abuja ti lo ọdún 49 láyé - Bàbá Flight Sergent Olasunkanmi
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Ẹ leè bẹ̀rẹ̀ sí ni gba afárá Third mainland Bridge padà báyìí, ó ti di ṣísí - Fasola