You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Third Mainland bridge open now: Afrárá Third Mainland di ṣíṣí padà lẹ̀yìn oṣù méje
Ijọba apappọ ti ṣi afara Third Mainland to wa niluu Eko fun lilo pada fun awọn olugbe ipinlẹ ọhun lẹyin ti wọn ti i fun atunṣe oloṣu meje.
Ṣaaju ni minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola ti kọkọ kede loju opo Twitter pe afara naa yoo di ṣisi laago mejila ọsan ọjọ Abamẹta.
Fashola ni "iṣẹ atunṣe afara Third Mainland ti pari. Yoo si di ṣiṣi ni aago mejila ọsan oni, ẹseun fun suuru yin, ki ẹ si rọra maa wa ọkọ loju popo."
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2020 ni ijọba apapọ gbe afara naa ti pa fun atunṣe pataki.
Lẹyin ti iṣẹ naa bẹrẹ ni wọn kede afikun oṣu kan si iṣẹ ọhun nitori iwọde #EndSARS.
Wọn pin atunṣẹ naa si abala meji, ti wọn si yan oṣu mẹta-mẹta fun abala kọọkan, bẹrẹ lati ọna Oworonsoki, ṣugbọn oṣu mẹrin ni wọn fi ṣe abala akọkọ naa.
Ni bayii ti wọn ti ṣi afara Third Mainland fun lilo, ireti wa pe irora awọn awakọ yoo dinku nipinlẹ Eko, paapaa awọn to n gba ori afara ọhun lojojumọ.