Kagara Students: Àwọn ajínigbé ti tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀

Iroyin to n jade lọwọ lọwọ sọ pe awọn ajinigbe ti tu awọn akẹkọọ Government Science Secondary School Kagara ni ijọba ibilẹ Rafi, ipinlẹ Niger silẹ bayii.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ lo fi aridaju naa han fun ile iṣẹ iroyin Channels TV pe awọn ọmọ naa ti wa ni opopona Minna tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.

Wọn ni ireti wa pe gomina Abubakar Bello ni yoo ki wọn kaabọ nile ijọba ipinlẹ naa ni Minna.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin yii wa fun un yin.