Ruga Settlement: Iléeṣẹ́ ààrẹ ní àgbékalẹ̀ àgọ́ Fulani lọ̀nà àbáyọ sí wàhálà àgbẹ̀ àti Fulani

Ileeṣẹ aarẹ orileede Naijiria ni ohun iyalẹnu lo jẹ fawọn bi awọn Gomina ipinlẹ kan ti ṣe n tapa si idasilẹ agọ Fulani, eyi ti wọn pe ni ''Ruga Settlement.''

Wọn fi ọrọ yi sita lẹyin ti awọn Gomina ipinlẹ kan kilọ fun ijọba pe, ko ma ṣe daba lati da awọn agọ wọnyii silẹ lagbegbe awọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ aarẹ, Femi Adesina sọ fun BBC pe, awọn ni akọsilẹ ibi tawọn Gomina kan ti fọwọ si kikọ ọgba fun dida ẹran, lati fi dẹkun wahala to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adesina ni ''Ajọ to n ri si ọrọ ajẹ ṣe agbekalẹ igbimọ kan, ti wọn si ṣe abẹwo sawọn ipinlẹ kan nibi tawọn Gomina ti fọwọ si pe, ki wọn da awọn agọ yii silẹ lati dẹkun aawọ to ma n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Amọ Adesina ni jẹ iyalẹnu lo jẹ fun oun pẹlu oun ti wọn wa n sọ nisinyii''

O fikun pe ''akọsilẹ wa pe awọn Gomina kan ni ọna abayọ niyi, ti wọn ba wa n tapa si, ọna abayọ miran wo ni wọn fẹ ka lo?

Nigba ti BBC beere lọwọ Adesina nipa ọrọ tawọn kan sọ pe, Ruga Settlement yii yoo gba ilẹ lọwọ awọn onilẹ, Adesina fesi pada pe''Ẹnikẹni to ba sọ iru ọrọ yii, ikorira lo fi sọ, o si yẹ ki wọn lọ fọ ọkan iru ẹni bẹẹ mọ kuro ninu ero eleyamẹya gbogbo''

Lọjọ iṣẹgun ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom fesi si igbese yii lẹyin ti ileeṣẹ to n risi ọrọ eto ọgbin gbe katakata wa, lati bẹrẹ isẹagbekalẹ agọ Fulani ni ipinlẹ Benue.

Ortom sọ pe ''eebu lo jẹ si awọn eeyan ipinlẹ Benue ati pe awọn lodi si''

''Awa ko faramọ dida agọ Fulani silẹ ni ipinlẹ Benue tori pe, a ko ni ilẹ lati ya sọtọ fun awọn to fẹ fi ẹran jẹ''

Ortom kasẹ ọrọ nilẹ pe ''ọta ilọsiwaju ati alaafia lawọn to n pe fun idasilẹ agọ Fulani''