Osun: Àwọn ọ̀daràn tó ń d'àlú Ikire rú wọ gàù Ọlọ́pàá

Adari ẹgbẹ Oodua Peoples Congress ni ipinlẹ Osun ṣalaye bi awọn eeyan wọn ni ilu Ikire ṣe koju igara ọdaran mẹrin kan to n damuu awọn olugbe ilu naa atawọn arinrinajo opopona Ife si Ibadan.

OPC sọ pe lọjọru ọsẹ lẹyin ti wọ́n fẹsun kan pe awọn ọdaran naa ṣọṣẹ lẹyin Ile ẹjọ giga ti ilu Ikire to wa lẹba opopona ni ọwọ tẹ wọn.

Iroyin sọ pe oludari ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ naa Adedeji Aladesewa, ṣalaye pe ọmọ ẹgbẹ OPC nilu Ikire lo ṣaaju igbesẹ ọlọgbọn ti ọwọ fi tẹ ikọ ọdaran naa ati ẹni kan to jẹ bi ejika ti ko jẹ kaṣọ wọn o yẹ.

Aladesewa sọ pe ọwọ tẹ ọ̀kan ninu wọn nigba to n gbiyanju lati na papa bora kuro nibi iṣẹlẹ idigunjale kan, lẹyin naa lo mu awọn ẹgbẹ OPC lọ ibi kọlọfin wọn.

Bawo gan ni OPC ṣe ri wọn mu?

Aladesewa ṣalaye pe oun gba ipe pajawiri kan latọdọ aladugbo rẹ kan, Toyin Ilori ni nkan bii agogo meji oru lọjọ aje ti ile rẹ wa lẹyin ile ẹjọ giga ti ilu Ikire.

"Ki awọn ole naa to de ile rẹ, wọn ti kọlu ile meji mii. Wọn dira pẹlu ibọn, ada ati oogun". O ni "mo ba bẹ ẹgbọn mi kan to wa nile, a si jọ lọ si ibi ti ole ti n ja yii".

"Meji ninu awọn ole naa ti wọ inu ile Ilori ti ọkan ninu wọn si n ṣọna ni ita. Kete ti eyi to wa nita ri wa lo ke si awọn to ku rẹ ti wọn si fẹsẹ fẹ ẹ".

Aladesewa ni awọn gba tẹle wọn ti oun si ba ọkan ninu wọn. " A jọ rọ lu koto ṣugbọn mo di i mu gba gba. Mo di i lokun mo si gba ọrọ lẹnu rẹ."

Ẹni yii lo jẹwọ ibi ti awọn to ku rẹ wa. Nigba naa awọn ẹgbẹ figilante ilu Ikire ti dara pọ mọ Aladesewa ti wn si jọ lọ si ile ti awọn ọdaran to ku n sa pamọ si.

"Meji ninu wọn sa sinu orule ṣugbọn oloogun wọn ko lee gbera tori ẹsẹ rẹ kan yọnu.

Bayii ni a ṣe mu gbogbo wọn ti a si ko wọn le Ọlọpaa lọwọ".

Nibayii, iroyin sọ pe wọn ti dari wọn lọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ niluu Osogbo.