Divorce case: Ọkùnrin kan sọ fún iléẹjọ́ láti tú ìgbéyàwó rẹ̀ ká, torí ìyàwó rẹ̀ máa ń gbá a létí

Ọkunrin kan to jẹ oṣiṣẹ ijọba, Ọgbẹni Oyeniyi Oyedepo sọ fun ileẹjọ agbegbe to wa ni Mapo niluu Ibadan pe ki wọn tu igbeyawo ọdun mẹrinla laarin oun ati iyawo oun ka.

Idi abajọ ni pe Ọgbẹni Oyedepo ṣalaye fun ileẹjọ pe niṣe ni iyawo oun, Iyabo ma n digbaju ru oun nigba kugba toun ba ti ba awọn ọmọ mẹrin ti Eledua fi jinki awọn wi.

''Iyabo ti da igbeyawo ru pata pata, alaigbọran obinrin ni, bẹẹ ni ko si bọwọ fun mi rara,'' Oyedepo lo sọ bẹẹ.

Iyawo rẹ naa to jẹ oniṣowo ni faramọ wi pe ki ileẹjọ tu igbeyawo awọn ka.

Iyabo ni onidọti n ọkọ oun, kii tun ara ṣe lẹyin to ba tọju awọn ẹranko to n sin tan ninu ile.

''Otitọ ni mo gba eti ẹ ṣugbọn nitori o lu mi, o si ni ki n kuro nile oun ni mo fi ṣe bẹẹ,'' Iyabo ṣalaye.

Iyabo fikun ọrọ rẹ pe Oyedepo tun n ṣe ṣina, nitori naa oun ko ni ifẹ rẹ mọ.

Aarẹ ileẹjọ ọhun, Oloye Ademola Odunade woye pe igbeyawo naa si le duro tawọn mejeeji ba ni suuru.

Aarẹ Odunade ranṣẹ pe awọn ẹbi ọkọ ati iyawo lati da si ọrọ naa.

Ileẹjọ ti sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii.