You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Daddy Freeze ti sọ̀rọ̀ lórí ẹjọ́ àgbèrè tó ṣe pẹ̀lú ìyàwó Paul Odekina, Benedicta Elechi
Gbajugbaja Agbohunsafẹfẹ, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ eyan mọ si Daddy Freez ti kede pe oun n lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun, lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ rivers ni ko san owo itanran nitori pe o ṣe agbere pẹlu iyawo oniyawo, Benedicta Elechi.
Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Youtube ni alẹ ọjọ Satide ni Daddy Freeze ti sọrọ lori idajọ naa.
O ni ile ẹjọ ko fi iwe kankan ranṣẹ si oun.
Bakan naa lo sọ pe oun ko ni sọ ohunkohun nipa awọn ẹsun to jẹyọ ninu idajọ naa, nitori pe ọrọ ti wa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Ṣugbọn lori ikọsilẹ to waye laarin oun ati iyawo rẹ nigba kan, Opeyemi Morenike Oni, Freeze sọ pe kii ṣe agbere tabi aarun ọpọlọ lo tu igbeyawo naa ka, gẹgẹ bi nkan ti obinrin ọhun n sọ kiri.
O ni iwa ipa ninu ile lo tu awọn ka.
Ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin jade pe ile ẹjọ giga kan to wa ni ili Port Harcourt nipinlẹ Rivers, dajọ ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2021, pe ki Ifedayo Olarinde san miliọnu marun-un Naira fun Paul Odekina, to jẹ ọkọ Benedicta Elechi to ṣe agbere pẹlu Freeze lasiko to ṣi wa nile ọkọ.
Onidajọ Akpughunum sọ pe ki Daddy Freeze san miliọnu marun-un naa jẹ owo itanran fun Odekina, nitori pe ko jẹ ko gbadun iyawo rẹ.
Bakan naa ni adajọ tu igbeyawo ka laarin Paul ati Benedicta nitori agbere ti Benedicta ṣe pẹlu Freeze.
Iroyin sọ pe agbere naa bi ọmọkunrin kan laarin wọn.
Yatọ si pe Daddy Freeze jẹ gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ni Naijiria, o tun gbajumọ fun bo ṣe ma n sọrọ tako awọn pasitọ, paapaa lori ọrọ idamẹwa ati ọrẹ.
O ti sọrọ abuku si awọn pasitọ bi David Oyedepo ti ijọ Winners Chapel, Pasitọ Enoch Adeboye ti ijọ Redeem ati awọn pasitọ nla mii.
Koda, o da ẹgbẹ kan silẹ to pe ni 'Free the Sheeple Movement' lati ma a 'tu awọn eeyan silẹ kuro ninu ide awọn pasitọ'.