You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Israel Adesanya fìdí rẹmi lọ́wọ́ Blachowicz ní ìdíje UFC259
Abẹsẹkubiojo ọmọ Naijiria Israel Adesanya ko ribi jẹwọ ara rẹ bi ọmọ Akin pẹlu bo ti ṣe padanu anfaani lati ni igbanu ẹyẹ, bẹliti meji lẹẹkan ṣoṣo ninu idije UFC259.
O kuna pẹlu bi alatako rẹ Jan Blachowicz ṣe fidi rẹ janlẹ ninu ija wọn to waye ni Las Vegas lọjọ Aiku.
Ninu abala marun un ija naa, awọn adajọ sọ pe Blachowicz lẹni to ṣe daada julọ pẹlu awọn ẹsẹ to rọ bo Adesanya.
Ni bayi, Blachowicz ṣi yi di bẹliti light heavyweight rẹ mu ti Adesanya naa si duro lẹgbẹ kẹjẹbu rẹ tii ṣe middleweight.
Ninu ọrọ rẹ to sọ lẹyin ija naa, Adesanya ni ko saburu nibi ifidirẹmi naa nitori igbiyanju loun gba lati fi itan lelẹ.
O ni lootọ ni Blachowicz tobi ju oun lọ ati pe o yẹ ki oun ṣapa ju bi oun ti ṣe ṣe lọ.
Igba akọkọ ree ti abẹsẹkubiojo naa yoo fidirẹmi lọwọ awọn alatako rẹ ninu idije UFC.
Kini awọn eeyan n sọ nipa ija yi?
Awọn ololufẹ Adesanya kan sara si pẹlu bo ti ṣe koju Blachowicz to tobi ju lọ.
Amar_23 ninu ọrọ rẹ ni ko saburu bi Izzy ti ṣe fidirẹmi nitori o gbiyanju lati sun siwaju kuro ni ipele to wa
Chisanga Malata ni akinkanju ni Adesanya ti o si yẹ kawọn eeyan gboṣuba kaare fun un.