Biola Fowosere skit: Ọ̀rọ̀ Biola Fowosere ati olùdarí èré n tako ara wọn lórí pé kó wọ aṣọ oníhòhò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Opo eeyan lo ti pe akiyesi mi si fidio yii, ṣugbọn....- Yeye Toyin Tomato

Orọ fidio to n ja ranyinranyin nile nipa Ewatomi ati oludari ere to ni ko wọ aṣọ onihoho yii lo ti n bi Ige ati Adubi.Ṣé 'skit' àbí òótọ ni bí olùdárí eré ṣe ni dandan ni kí Biola Fowosere wọ aṣọ oníhòhò? Ohun ti a mọ̀ rèé

Leyin o rẹyin gbogbo oro naa ni awọn agbaagba oṣere ti n ba wọn da sii.

Lara awọn to ti da si ọrọ naa ni Yeye Toyin Adegbola.

O ni pe Adebayo Ajiboye to jẹ oludari ere naa mọ Biola Fowosere daadaa ati pe Ewatomi kii ṣe alainile tabi mọto rara.

Yeye Toyin ni pe 'Skit'lasan ni wọn n ṣe fun awada awọn ololufẹ wọn.

Bakan naa ni ero awọn ọmọ Naijiria ṣọtọọtọ si iṣẹlẹ naa.

Bi awọn kan ṣe ti n gboriyin fun Ewatomi naa ni awọn mii ni pe o jẹ ere tabi kii ṣe ere ko kan wọn bikoṣe pe ki awọn oṣere Yoruba yee wọ aṣọ iwọkuwọ mọ.

Yeye Toyin tomatoes ni ki awọn eeyan dẹkun idẹyési oludari ere naa nitori ko ṣe Ewatomi rara.

Ṣé 'skit' àbí òótọ ni bí olùdárí eré ṣe ni dandan ni kí Biola Fowosere wọ aṣọ oníhòhò? Ohun ti a mọ̀ rèé

Awuyewuye ko tii sinmi, lori fidio kan ti oṣerebinrin, Biola Fowosere, fi sita pe adari ere kan ni ki oun fi tipatipa wa ni ihoho ninu fiimu kan.

Ninu fidio naa la ti ri Biola to n fi itara sọrọ pe ko si ohunkohun to le mu ki oun ṣi ara silẹ tabi wa ni ihoho ninu fiimu .

O ni olori ayaba gidi ni wọn sọ fun oun pe oun yoo ṣe ninu sinima naa ti wọn pe akọle rẹ ni Oloṣo L'aafin.

O ni ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun de ẹnu iṣẹ, ti oludari ere naa sọ pe oun ko gbọdọ wọ awọn aṣọ ti oun ko wa, ayaafi eyi ti yoo ṣi ara silẹ.

Biola, to n fi ibinu sọrọ ninu fidio naa sọ pe oun ṣetan lati da owo iṣẹ ti wọn san fun oun pada, dipo ki oun ṣi ara silẹ.

"Olori aafin ni wọn sọ pe ma a ṣe, kii sẹ aṣẹwo."

Ninu fidio naa ni oludari ere, ti wọn pe orukọ rẹ ni Bayo, ti bu Biola pe wiwa ni ihoho ati ṣiṣi ara silẹ, ni awọn oṣerebinrin fi n pawo.

Ati pe nitori pe Biola kii ṣe bẹẹ, ni ko ṣe ri owo kọle tabi ra mọto lati ọdun to ti n ṣiṣẹ.

Ọrọ yii dun biola debi pe o bu sẹkun, ti awọn akẹẹgbẹ sẹ to wa nibẹ si n rọ ọ pe ko ṣe nkan ti oludari ere fẹ.

Amọ gbogbo ẹbẹ ati arọwa ti awọn oṣere akẹẹgbẹ rẹ ṣe ko tu irun kankan lara Biola rara.

Awuyewuye tẹle fidio ti Biola Fowosere fi sita

Lẹyin ti fidio naa jade sori ayelujara, awuyewuye tẹle. Bi ọpọ ṣe n gboriyin fun oṣerebinrin na fun iwa ọmọluabi to hu, nipa pe ko ṣi ara rẹ silẹ ninu sinima.

Ni awọn kan n koro oju si bi oludari ere naa ṣe fẹ lu Biola, to si tun ja kọkọrọ ọkọ to gbe wa sibi iṣẹ naa gba.

'Skit ni fidio naa, Bayo ko fiya jẹ mi'

Ko pẹ ti fidio akọkọ jade, ni Biola tun fi fidio miran sita pe iṣẹlẹ naa kii ṣe ootọ.

O ni awọn ya fidio naa lati fi polongo sinima tuntun ti wọn n ya ni, to si bẹ awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn o ma binu si oun lori ẹtanjẹ naa.

Bo sẹ sọ ọrọ yii ni awọn ololufẹ rẹ kan bẹrẹ si ni koro oju si pe ko bojumu bo ṣe kọkọ parọ. Wọn ni eyi yoo mu ko ṣoro fun lati ri iranlọwọ gba ni ọjọ iwaju.

Awọn ti ẹ sọ pe awọn ko gbagbọ pe 'skit' ni fidio naa, ati pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe awọn agbalagba ninu iṣẹ tiata lo paṣẹ fun pe ko parọ pe iṣẹlẹ naa ko waye.

Oludari ere, Bayo, sọ pe Biola fẹ ba aye oun jẹ ni

Ko pẹ ti Arabinrin Biola fi fidio naa sita lọjọ Aiku, ni oludari ere naa, Ọgbẹni Bayo, naa fi fidio kan sita lati sọ pe oun ko mọ nkankan nipa 'skit' naa.

O ni ibi ti oun ti n dari iṣẹ naa ni oun wa nigba ti Biola Fowosere wa ba oun pe awọn fẹ ya fidio 'skit' kan, lati ṣe ipolowo fun fiimu 'Oloṣo l'aafin'.

Ọgbẹni Bayo ṣalaye pe Biola funra rẹ lo kọ oun ni gbogbo ọrọ ti oun sọ ati iwa ti oun wù si ninu fidio to di awuyewuye.

"Ọtọ ni nkan ti Biola Fowosere sọ fun mi pe oun yoo kọ gẹgẹ bi akọle fidio naa - lati sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe ere ni a n ṣe.

"Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun mi nigba ti mo ri pe o parọ mọ mi pe mo fi ipa mu lati bọ aṣọ silẹ."

"Mi o mọ nkan ti mo sẹ fun to fi fẹ ba aye mi jẹ, nitori lati ọjọ naa ni awọn eeyan ti n pe mi, ti wọn si n bu mi"

Biola sọ bi ọrọ ṣe jẹ gan-an

Ọrọ ti Ọgbẹni Bayo sọ yii ko ba Arabinrin Biola lara mu rara. Niṣe ni oun naa tun fi fidio miran sita, nibi to ti ṣẹ ọpọlọpọ epe lati wẹ ara rẹ mọ

O ni oun gbiynaju lati wẹ Arakunrin Bayo mọ́, ni oun fi ṣe fidio pe 'skit' ni fidio ti Bayo ti fiya jẹ oun, nitori bi awọn eeyan kan ṣe bẹ oun lati dakẹ lori ọrọ naa.

Bakan naa lo koro oju si bi Bayo ṣe ni o fẹ ba aye oun jẹ ni, pẹlu irọ to pa.

Ko tii daju pe awuyewuye yoo dakẹ lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni a ko tii le sọ ẹni to n sọ otitọ̀ ninu awọn mejeeji.

Ninu ọrọ to sọ fun BBC ni owurọ ọjọ Aje, Biola sọ pe 'skit' ni awọn n ṣe, ati pe oun ko fẹ ṣe ifọrọwanilẹnuwo kankan lori ọrọ naa.