Ìyálé Mercy Aigbe kìlọ̀ fún un pé kó yé ya àwòrán nínú ilé tí òun fi ìláàgùn kọ́, ọkọ rẹ̀ fún un lésì…

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin to wa lori ẹrọ ayelujara ti fihan gbangba pe nkan ko lọ deede laarin gbajugbaja oṣerebinrin, Mercy Aigbe ati iyaale rẹ, Funsho Adeoti.

Mercy Aigbe to jẹ iyawo keji Kazim Adeoti to n gbe fiimu jade, ni iyaale rẹ ti kilọ fun lori ẹrọ Instagram rẹ.

Ni Ọjọ Aje ni Funsho Adeoti kilọ fun ọkọ ati iyawo tuntun pe ki wọn ye ya aworan ati fidio ninu ile oun.

Bawo ni akara ṣe tu si epo lori ẹrọ ayelujara?

Funsho to ti bi ọmọ mẹrin naa ni oun ti kọkọ kilọ fun ọkọ oun ni kọrọ pe ko sọ fun Mercy Aigbe ko ye ya fọtọ ni inu ile wọn mọ.

O ni nitori igba miran to ba tun ṣe iru rẹ, oun yoo ṣe yẹyẹ wọn ni ita gbangba.

Ninu akọjade loju opo rẹ to ti yọ kuro bayii lo ti sọ pe;

''Ti Mercy Aigbe ba tun ya fọto ni inu ile ti oun ṣe iṣẹ fun, to si fi si ẹrọ ayelujara, oun yoo ri pe oun tu ihoho wọn si ita lori ẹrọ ayelujara.''

Amọ ọkọ iyawo naa lasiko to n fesi si ohun ti iyawo rẹ akọkọ sọ, lo ti ni ko si otitọ kankan ninu iroyin ti iyawo oun gbe jade nipa oun ati idile oun.

O ni irọ patapata ni , ti ko si otitọ kankan nibẹ, ti iyawo oun si ti n binu lati igba ti oun ti fẹ Mercy Aigbe gẹgẹ bi iyawo keji.

Emi fun ara mi ni mo kọ ile mi- Ọkọ Mercy Aigbe:

Ọkọ Aigbe ni ''Bio tilẹ jẹ pe ko si ohun to buru ninu ki ọkọ ati iyawo fọwọsowọpọ kọ ile papọ, amọ ni ile temi, ọrọ ko ri bẹẹ. Emi fun ara mi ni mo kọ ile mi.''

O fikun un pe bi iyawo oun akọkọ ṣe ra nkan mere mere si inu ile, ni iyawo oun keji naa ra awọn nkan si inu ile, ti oun si ti da lara owo iyawo oun akọkọ naa pada.

''Bio tilẹ jẹpe nko fẹran lati maa tabuku awọn eniyan to jẹ ọrẹ mi nigba kan ri to fi mọ iyawo mi akọkọ.''

''Mi o ni tabuku rẹ ni igba kankan nitori iyawo mi ni ni ọjọkọjọ ni ati nitori awọn ọmọ wa.''

Ọpọ eniyan lo fi ero wọn han, ti iroyin wọn si gba ori ayelujara kan nigba ti Mercy Aigbe kede pe oun ti di iyawo keji ni ile Adeoti ni Oṣu Kẹta, ọdun 2022.