Gorillas in Nigeria: Orí àwọn Ìnàkí náà kéré, ọwọ́ wọn gùn, tí irun wọn sì funfun

Oríṣun àwòrán, WCS
Wọn ti gbe aworan awọn inaki kan jade lori ayelujara fun igba akọkọ ni ọpọ ọdun.
Awọn inaki naa ti wọn ri ni ipinlẹ Crosss River, ni awọn to n ri si ọrọ itọju ẹranko sọ pe o ṣọwọn lagbaye.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ko ju ọọdunrun iru inaki bẹẹ pere to wa ninu aginju ti wọn ti ri wọn, to n tumọ si pe ẹmi awọn ẹranko ọhun wa ninu ewu.
Ẹgbẹ awọn to n ṣetọju ẹranko ni Naijiria, WCS sọ pe, o ṣeeṣe ki awọn ẹranko naa maa bimọ sii, ki ẹya wọn ma baa parun.
WCS ni ẹrọ ayaworan ti wọn ri mọlẹ ninu aginju ọhun, lo ya aworan awọn Inaki naa, ti diẹ lara wọn si ni ọmọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, WCS Nigeria
Ajọ to n ṣakojọpọ owo fun itọju ohun adayeba lagbaye, WWF sọ pe, irufẹ awọn inaki ti wọn ri ni ipinlẹ Cross River naa lo ṣọwọn julọ lagbaye.
WWF ni awọn inaki naa n sa fun eeyan, bẹẹ ni iyatọ diẹ wa laarin wọn atawọn inaki miran, fun apẹẹrẹ, ori wọn kere, ọwọ wọn gun, bẹẹ naa ni irun ara wọn funfun diẹ ju ti awọn inaki mii lọ.

Oríṣun àwòrán, WCS Nigeria
Iroyin ni awọn ẹranko naa n gbe lawọn ibi to ni oke giga ni Naijiria, ati ni orilẹ-ede Cameroon, ṣugbọn wọn ṣoro lati ri.
Wayi o, WCS ni iṣẹ ti bẹrẹ pẹlu ajọṣepọ ijọba Naijiria atawọn ti ọrọ kan, lati daabo bo awọn ẹranko ọhun.
- Àṣírí tú! Ẹ̀rọ ayàwòrán ara ọlọ́pàá fihàn pé ìgbà ogún ni George Floyd pariwo, kó tó kú
- Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye












