Ondo curfew: Ìjọba kéde òfin kónlé-ó-gbélé ní Igbara-Oke lẹ́yìn tí rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lórí ìbò kánsílọ̀

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede ofin konle-o-gbele ọlọjọ kan niluu Igbara-Oke tii ṣe ibujoko ijọba ibilẹ Ifedore nipinlẹ naa.

Gomina Akeredolu kede ofin konle-o-gbele nibẹ lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ lori esi ibo kansilọ to waye ni ijọba ibilẹ naa.

Akọwe iroyin fun gomina Ondo, Richard Olatunde, lo fi ọrọ naa lede niluu Akure.

Akeredolu ni aṣẹ naa ti mulẹ nin kiakia, bakan naa lo paṣẹ fawọn oṣiṣẹ eleto abo lati ri pe awọn araalu tẹ le ofin konle-o-gbele ọhun ki alaafia le jọba.

Gomina ipinlẹ Ondo tun rọ awọn ọba alade atawọn alẹnulọrọ to fi mọ gbogbo awọn tọrọ kan lati kilọ fawọn ọmọlẹyin wọn pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.

Gomina Akeredolu ni ijọba ko ni fi oju 're wo ẹnikẹni to ba tapa si ofin konle-o-gbele naa.

Ifẹhonuhan lo kọkọ bẹrẹ niluu Igbara Oke lẹyin eto idibo kansilọ to waye ki ọrọ naa to di nla.