Buhari: Aó wá àwọn olóṣèlú tó n fa rògbòdìyàn ní àwárí

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ti di ẹbi awọn rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni Naijiria ru awọn oloṣelu tinu n bi.
Buhari sọrọ naa lasiko to n kopa nibi ayẹyẹ ayajọ ileesẹ ologun, to waye ni ipinlẹ Borno.
Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki fun un lori eto iroyin, Bashir ahmad fi sita lori Twitter, Buhari, bo tilẹ jẹ wipe ko tọka si rogbodiyan tawọn oloṣelu tinu n bi fa, O ni:
"Ọpọlọpọ rogbodiyan lo ti waye ni awọn ipinlẹ kan, eleyi ti awọn oloṣelu tinu n bi, to si ti kuna ni gbogbo ọna, mọọ-mọ ṣe agbatẹru rẹ, pẹlu bi wọn ṣe n wa gbogbo ọna lati da wahala silẹ gẹgẹ bi ọna lati polongo ara wọn"
"A o wa wọn ri, a o si fi iya jẹ wọn gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.'"
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bẹ́ẹ̀ bá sì gbàgbé, onírúurú rògbòdìyàn ló ti wáyé ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, èyí tó ti mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ.








