Iléẹjọ́: Buhari gbọdọ̀ dènà N40bn táwọn asòfin fẹ́ mú nínú ìsúná

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate
Iléẹ́jọ gíga ìjọba àpapọ̀ tó kalẹ̀ sí ìlú Èkó ti pàsẹ pé, kí wọn tètè fi ojú àwọn asaájú ilé asòfin, tí wọn fẹ̀sùn kàn pé, wọn de ìdí fún ètò ìsúná ọdún 2016, tó fi fò sókè pẹ̀lú owó tótó mílíọ́nù lọ́nà ọ̀rìnlénírinwó ó lé ẹyọ kan naira, ba iléẹjọ́ lẹ́yẹ ò sọkà.
Adájọ́ Mohammed Idris tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ tún ní ààrẹ Muhammadu Buhari gbọdọ̀ pàsẹ fáwọn iléisẹ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu, tí wọn tanná wadìí ẹ̀sùn síse àfikún ètò ìsúná náà, láti gbé àbọ̀ wọn kalẹ̀ sí iwájú òun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adájọ́ Idris gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹjọ́ tí àjọ tó ń rísí ètò ìjíyìn isẹ́ ìríjú ẹni, SERAP pè láti jẹ́kí ìjọba àpapọ̀ fojú àwọn asòfin tó gbé owó ìsúná 2016 sókè, balé ẹjọ́.
Adájọ́ náà tún pàsẹ pé kí ààrẹ Buhari "tètè dènà ète àwọn asaájú ilé asòfin àpapọ̀ kan láti jí ogójì bílíọ́nù naira nínú ọgọ́rùn-ún bílíọ́nù tí ìjọba rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún àwọn asòfin náà láti fi pèsè ohun èèlò amáyédẹrùn fún ẹkùn ìdìbò wọn lọ́dún 2017."

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate
Nígbà tó ń fèsì lórí ìdájọ́ náà, igbákejì olùdarí fájọ SERAP, Timothy Adewale ni "ìdájọ́ náà ló fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìwà àjẹbánu gogò ní ìdí ètò ìsúná wa, tí àsà ‘taa ni yóò mú mi’ sì di tọ́rọ́ fọ́n kálé láàrin àwọn asòfin wa, tó fi mọ́ ìkùnà àwọn alásẹ láti máse fi igbá kan bo ọ̀kan nínú, nínú ìlànà ètò ìsúná wa àti ìmúsẹ rẹ̀."









