Akungba Akoko Accident: Ọkọ̀ ńlá míì tún ti ṣekú pa àkẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Adekunle Ajasin ni Ondo, ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga Adekunle Ajasin, Akungba, ìpínlẹ̀ Ondo ti kọminú lórí bí ìjàmbá ọkọ̀ ṣe ń ṣekúpa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ní gbogbo ìgbà.
Alákoso ìfitóni létí ọ̀rọ̀ tó ń lọ ilé ẹ̀kọ́ náà, Olugbenga Arajulu nínú àtẹ̀jáde kan ní ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣokùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ọjọ́'Bọ̀ jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́ púpọ̀.
Fún ìdí èyí, ilé ẹ̀kọ́ náà ti sún ìdánwò tó yẹ ló wáyé lónìí, ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrin, oṣù keji síwájú dí ọjọ́ mìíràn tí wọn kò tíì kéde.Ọkọ̀ ńlá míì tún ti ṣekú pa àkẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Adekunle Ajasin ni Ondo, ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Bákan náà ló ní àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti wá bí òpin yóò ṣe dé bá bí ìjàmbá ọks ṣe máa ń wáyé ní ẹnu ọ̀nà ilé ẹ̀kọ́ náà.
- ''Àwa ẹgbẹ́ Agbekoya ṣetán láti tú Sunday Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n pẹ̀lú agbára àwọn àgba''
- Ètò Ìsìnkú olóògbé Ernest Shonekan ti ń wáyé báyìí
- Wàhálà tún bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ hìjábù ní Kwara, ìjọba ti iléẹ̀kọ́ Baptist ní Oyun pa
- Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀
- Èèyàn 26 kú nígbà tí wáyà iná já lé wọn lórí láàrin ọjà

Oríṣun àwòrán, @Ondo Govt
Ọkọ̀ ńlá míì tún ti ṣekú pa àkẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Adekunle Ajasin ni Ondo, ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé
Awọn akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin ni ipinlẹ Ondo ti bọ sori ori ayelujara lati bẹnu atẹ lu isẹlẹ ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe ile ẹkọ wọn.
Ninu isẹlẹ yi, eeyan mẹta gẹgẹ bi iroyin ti se sọ, padanu ẹmi wọn nigba ti ọkọ tirela kan ya lọ ba awọn akẹkọọ.
Irọlẹ Ọjọbọ ni isẹlẹ ijamba ọkọ yi waye.
Gẹgẹ bi a ti se gbọ, ọkan ninu awọn akẹkọọ to ku yi n palẹmọ eto Isinru NYSC lẹyin to pari ẹkọ rẹ.
- Àwọn ọmọ ogun America pa olórí ISIS, Ibrahim al-Qurayshi ní Syria
- Wàhálà tún bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ hìjábù ní Kwara, ìjọba ti iléẹ̀kọ́ Baptist ní Oyun pa
- Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀
- Èèyàn 26 kú nígbà tí wáyà iná já lé wọn lórí láàrin ọjà
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọkùnrin mẹ́rin tó fi olólùfẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣe òògùn owó sí ẹ̀wọ̀n
- Ọ̀gá àgbà NSCDC dá àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ náà tó wà pẹ̀lú Shina Peller padà
Nibo ni ọrọ de duro bayii?
Lasiko ta fi n ko iroyin yi jọ, awọn alasẹ fasiti naa ko ti sọrọ lori isẹlẹ naa.
Loju opo ayelujara ni awọn akẹkọọ fasiti naa ti gbode kan pẹlu hashtag #SaveAAUA #SaveAkungba ti wọn si lawọn n kesi awọn alasẹ lati doola awọn akẹkọọ lọwọ iku gbona.
Wọn ni ki wọn sọ titi to kọja niwaju ile ẹkọ naa di onibeji ki wọn si wọ ilẹ titi to gba iwaju ile ẹkọ naa nitori pe o da firi walẹ pupọ.
'Ẹgbẹ akẹkọọ lawọn n gbero iwọde alaafia
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Igba akọkọ kọ yi ti iru isẹlẹ ijamba ọkọ yi yoo waye ni ile ẹkọ Fasiti Adekunle Ajasin,Akungba.
Ni ọjọ kejilelogun osu kini ọdun 2021 wọn ti ile ẹkọ naa pa nitori bawọn akẹkọọ se gbegi dina nitori awọn akẹkọọ ti tirela ya lọ ba niwaju ile ẹkọ naa.
O kere tan eeyan mẹjọ lo ba ijamba ọkọ yi lalẹ ọjọ to waye nigba naa lọhun.
Iroyin sọ pe tirela nla kan to ko simẹnti ni ijanu rẹ kọsẹ to si rọ lu awọn sọọbu itaja to wa ni tosi ibi tawọn akẹkọọ n gbe.
Ọkọ tirela nla kan, ọkọ bọọsi korope Suzuki kan ati ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kan ni o faragba ninu isẹlẹ yi.
Lapapọ ero mejidinlogun lọrọ yi kan.
Ọpọ awọn akẹkọọ lo farapa ninu isẹlẹ to waye saaju eleyi to mu ki awọn akẹkọọ fẹ se iwọde nitori eyi to tun waye nisinyi.
Ọkan lara awọn akẹkọọ jade fasiti yi sọ fun BBC pe isẹlẹ iru eleyi ko jẹ tuntun lagbegbe naa nitori pe oju ọna ibi ti ileẹkọ naa wa ko jina si ori oke.
Bi ọkọ baa n da firi bọ, rẹgi lo maa n nse pẹlu ibi tawọn akẹkọọ n duro si lati wọ ọkọ.
A o maa fi to yin leti bi isẹlẹ yi ba se n lọ si.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo
- Ìdí rèé tí Yahaya Bello fi gbọdọ̀ dá Amotekun sílẹ̀ ní Kogi- Gani Adams
- Àjọ SERAP gbé Ààrẹ Buhari lọ sílé ẹjọ́ nítorì kò wádìí N3B tó pòórá níléèṣẹ̀ ètò ẹ̀náwó
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
















