You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iyabo Ojo: Ẹ kílò fún Yomi Fabiyi àti àwọn àgbààgbà ẹgbé tó kọ́pa nínú fíímú ''Oko Iyabo''!
Ori ayelujara gbona jainjain lati ọjọ ti oṣere Yomi Fabiyi ti gbe fiimu tuntun jade 'Ọkọ Iyabo'', eleyii to farapẹ iṣẹlẹ Baba Ijesha ati ọmọdebinrin to ṣe aṣemaṣe pẹlu rẹ.
Niṣe ni awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu fiimu naa, ti wọn ṣi n fi oko ọrọ ranṣẹ si Yomi Fabiyi fun ara rẹ.
Lara awọn to sọrọ tako fiimu naa ni iyabo Ojo atawọn akẹẹgbẹ rẹ miran bi Mercy Aigbe to fesi lori awọn afarajọ to wa ninu fiimu naa.
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Bimpe Oyebade tú àṣírí bí Yomi ṣe ń gbógun tìí torí ìbalòpọ̀
- Tá ló yọ fíímù Yomi Fabiyi ''Oko Iyabo'' kúrò lójú Youtube, Instagram?
- Yomi Fabiyi wọ wàhálà ẹgbẹ́ TAMPAN torí fíìmù Ọkọ Iyabọ
- Yomi Fabiyi ṣe fíìmù lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Iyabo ló dá lé lórí
- Àwọn daran-daran ní Nàìjíríà ní ẹgbẹ́ wọ́n sì ní olórí ṣùgbọ́n ẹ kọ̀ láti mú olórí wọn - Wole Soyinka
- "Ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ TB Joshua ló mú mi bí ọmọ mi wẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀"
- Ẹkùn Gúúsù Nàìjíríà ni ààrẹ gbọdọ̀ ti wá lọ́dún 2023 - Àwọn Gómìnà Gúúsù yarí
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
Ọpọ awọn osere tiata to wo fiimu naa si lo faraya pe ko tọ ki Yomi Fabiyi wọ akẹẹgbẹ rẹ nilẹ bii eyi.
Nibayii, oju opo Youtube ti wọn gbe fiimu naa wọn si ti wọgile kuro nibẹ.
Amọ̀ sibẹ sibẹ Yomi Fabiyi ni oun se fiimu naa lati la awọn eeyan lọyẹ lori ẹtọ ti wọn ni labẹ ofin ni.
Yomi Fabiyi wọ wàhálà ẹgbẹ́ TAMPAN torí fíìmù Ọkọ Iyabọ
Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn osẹre tiata ni Naijiria, TAMPAN, ti ranṣẹ pe ọkan lara wọn, Yomi Fabiyi lati wa a rojọ.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ TAMPAN fi sita lọjọ Aje lo ti sọ pe, igbimọ to ma n yanju ikunsinu ninu ẹgbẹ naa lo ranṣẹ pe Fabiyi, lẹyin to gbe fiimu tuntun to pe ni 'Ọkọ Iyabọ' jade.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2021 ni Fabiyi kede pe fiimu naa ti di nkan ti awọn ololufẹ oun le ma a wo lori ayelujara Youtube.
O ti n polongo fiimu naa lati ọsẹ diẹ sẹyin.
Lati igba to si ti kede pe fiimu naa ti jade, ni ọpọ eeyan ti n koro oju si, paapaa nitori orukọ to fi sọ ọ.
Tẹ o ba gbagbe, ẹ o ranti pe Yomi Fabiyi ati akẹẹgbẹ rẹ kan, Iyabo Ojo, jọ ta ohun si ara wọn fun ọpọlọpọ ọjọ nitori ọrọ akẹẹgbẹ wọn, Lanre Omiyinka Baba Ijesha, ti wọn mu fun ẹsun fifi ipa ba ọmọde lopọ.
Ninu oṣu Kẹrin ni ọwọ tẹ Baba Ijesha nile obinrin apanilẹrin, Princess Comedian, pe o n ba ọmọ kan to n gbe lọdọ rẹ ni ajọṣepọ ti ko tọ ọ.
Akiyesi BBC Yoruba nipa fiimu ti Fabiyi gbe jade yii fihan pe lori ọrọ ẹsun Baba Ijesha lo da le lori.
Paapaa julọ pe o fi pa aroko ọrọ ranṣẹ si ẹni ti ko darukọ, nitori pe Iyabọ lo pe orukọ ọmọbinrin to jẹ koko ninu fiimu naa, osẹre si tun ni.
Iṣẹ aṣẹwo ni ọmọbinrin naa n ṣe, to si tun ṣe oogun lati moke nidi iṣẹ tiata.
Ẹgbẹ TAMPAN sọ pe Fabiyi gbọdọ farahan niwaju igbimọ olubawi naa ni ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2021.
Wọn ni "pipe ti a pe di dandan nitori awuyewuye ti fiimu naa ti fa, eyi to tako ilana ati amuyẹ wa.
"A mọ pe fiimu naa tun ti fa wahala mii laarin ẹgbẹ TAMPAN ati awọn araalu, eyi kii ṣe itẹwọgba fun wa rara, o si tako nkan ti a duro fun."
Wọn ni awọn rọ gbogbo araalu lati ni suuru fun ẹgbẹ naa ko yanju ọrọ yii.