TB Joshua burial: Ètò ìsìnkú TB Joshua ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àṣálẹ́ àbẹ́là títàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ayẹyẹ eto isin idagbere ti bẹrẹ fun oloogbe Temitope Joshua ni ipinlẹ Eko ati ilu abinibi rẹ, Arigidi-Akoko nipinlẹ Ondo.

Eto aṣalẹ titan abẹla ni wọn fi bẹrẹ ayẹyẹ naa ni Arigidi, eyi ti ọpọ ọmọ ilu naa ati awọn ololufẹ rẹ ti kopa.

Kaluku wọn to mu abẹla ti wọn tàn dani lo daro rẹ, ti wọn si n fi awọn abẹla wọn silẹ ni ibi kan ti wọn ya sọtọ ni ile ti wọn ti bi oloogbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn eeyan to kopa nibi aṣalẹ abẹla titan ti wọn fi bẹrẹ isin idagbere fun oloogbe, Wolii Temitope Joshua ni ilu abinibi rẹ, Arabinrin Kemi Omoniyi, Arigidi-Akoko, ti sọ pe lootọ lo kú amọ isẹ iranṣẹ n tẹsiwaju.

Nibi eto naa ti akọroyin BBC Yoruba ti kopa, ni obinrin naa ti sọ pe o ma n nira fun oun lati bimọ ti oun ba loyun wọn.

O ni lọjọ ti iroyin iku TB Joshua jade, ibanujẹ lo jẹ fun oun nitori pe oun gbagbọ pe pẹlu iranlọwọ isẹ iransẹ rẹ, oun yoo bi oyun inu oun layọ.

O sọ pe bẹẹni oun bẹrẹ si ni gbadura pe to ba jẹ lootọ ni Ọlọrun pe TB Joshua, ki oun bimọ wẹrẹ.

Arabinrin Omoniyi sọ pe bẹẹ gẹlẹ lo ri fun oun ni ọjọ ti oun fẹ ẹ bimọ, debi pe oun ko ni irora kankan lasiko irọbi.

Emmanuel to jẹ ara orukọ oloogbe TB Joshua ni oun ati ọkọ rẹ to jọ wa sibi eto naa sọ ọmọ wọn lati bu ọla fun un.

Bí wọ́n ṣe n ṣe ètò ìsìnkú T. B Joshua l'Eko, làwa nàá yóò ń ṣe ní Arigidi - Zaki ìlú Arigidi

Zaki ilu Arigidi-Akoko ni ipinlẹ Ondo, to jẹ ilu abinibi oloogbe Wolii Temitope Joshua, Ọba Yisa Olanipekun, ti sọ pe oriṣiriṣi eto lo wa nilẹ fun isinku wolii naa.

Ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ni ayẹyẹ isinku T.B Joshua to di oloogbe ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, bẹrẹ nile ijọsin rẹ, Synagogue Church of All Nations, nipinlẹ Eko.

Ọba Olanipekun sọ pe gbogbo eto ati ayẹyẹ ti wọn ba ṣe ni Eko, naa ni yoo waye ni Arigidi

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn naa yoo bẹrẹ ayẹyẹ idagbere ni ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Keje, pẹlu alẹ abẹla titan, lasiko kan naa to ba n waye ni ile ijọsin Synagogue nipinlẹ Eko.

Ṣaaju ni Ọba Olanipekun ti fi erongba ọkan ara ilu Arigidi han pe ilu Arigidi ni awọn fẹ ki wọn o sin oku T.B Joshua si.