You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Baba Ijesha: TAMPAN pàṣẹ pé 'director' kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde sí iṣẹ́ mọ́
Damola Olatunji, alaga ẹgbẹ awọn oludari sinima, to jẹ ẹka ẹgbẹ TAMPAN, ti fesi pe ibawi ti wọn fun Nkechi Blessing ati Adams Kehinde 'Lege Miami', kii ṣe ojuṣaaju.
O sọ ọrọ yii lẹyin ti awuyewuye waye pe kilode ti ẹgbẹ naa ko fi iya kan naa jẹ Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi to ṣẹ ẹṣẹ kan naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olatunji sọ pe ọrọ Iyabo ati Fabiyi dabi ọrọ Yoruba to sọ pe ka kọkọ le ẹlẹyọrọ lọ tan, ka to o fi abọ ba adiyẹ.
O ni ọpọlọpọ igba ni ikilọ ti jade si awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN pe wọn ko gbọdọ wọ ara wọn tabi sọ ọrọ kobakungbe si ara wọn lori ayelujara.
"Nipa ti Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi, ọrọ ti wọn n ja si ti wa nile ẹjọ, o si di igba ti ile ẹjọ ba yanju ọrọ naa, ka to o mọ nkan ti a le sẹ.
"Ṣugbọn ti eeyan ba fẹ ẹ fọ ilu mọ, ibi kan ni yoo ti bẹrẹ. Ẹ jẹ ka gba pe ibi yii (Nkechi ati Adams) lati bẹrẹ."
Bakan naa lo sọ pe oun ko ti i le sọ igba tabi akoko ti ofin ti wọn fi de osẹre mejeeji yoo dopin. Olatunji sọ pe ẹgbẹ nikan lo le sọ.
Ọjọ Aiku ni Damola Olatunji fi ikede sita lorukọ ẹgbẹ awọn oludari ere ati TAMPAN pe, oludari ere kankan ko gbọdọ pe Nkechi Blessing Sunday ati Adams Kehinde 'Lege Miami' si ere , nitori pe wọn ta epo si aṣọ ala ẹgbẹ.
TAMPAN pàṣẹ pé 'director' kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde sí iṣẹ́ mọ́
Ẹgbẹ awọn oludari ere (director), to jẹ ẹka kan nini ẹgbẹ, Tampan Guild of Directors (TGD) ti paṣẹ pe ki oṣerebinrin, Sunday Nkechi Blessing ati oṣerekunrin, Adams Kehinde (Lege) lọ ọ rọọkun nile fun igba diẹ.
TGD jẹ ẹka kan ni abẹ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN.
Ikede yii jẹyọ ninu atẹjade ti Alaga igbimọ oludari naa, Damọla Ọlatunji fi sita ni alẹ ọjọ Aiku.
Ninu atẹjade naa, Ọlatunji sọ pe wọn ti pe akiyesi TAMPAN si iwa afojudi, sisọ ọrọ buruku si ara ẹni, ati awọn iwa mii, to n fa arinfin fun ẹgbẹ naa.
Igbesẹ ti ẹgbẹ TAMPAN gbe ko ṣẹyin bi awọn osẹre mejeeji ṣe n sọ ọrọ buruku si ara wọn lori ayelujara, nitori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijẹsha.
Lati igba ti iroyin ti jade pe ọwọ tẹ Omiyinka, ni awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ti n gbena woju ara wọn.
Bi awọn kan ṣe n ṣe atilẹyin fun, ni awọn to koro oju si ẹsun ti wọn fi kan an n ba wọn wi pe ki wọn o ma ṣatilẹyin fun iwa ibajẹ.
Lara awọn ti 'ija' wọn gba ori ayelujara ni Iyabọ Ojo ati Yọmi Fabiyi.
Botilẹ jẹ pe awuyewuye ti dakẹ diẹ lori ọrọ Baba Ijẹsha, ọjọ diẹ sẹyin tun ni Nkechi ati Lege tun ru ina ede aiyede to ti kọkọ waye laarin wọn nipa iṣẹlẹ naa soke.
Lẹyin ti Lege ti kọkọ tọrọ̀ aforiji fun awọn ọrọ to fi ṣatilẹyin fun Baba Ijẹsha, lo tun sọ pe Nkechi wu iwa arifin si oun lasiko naa.
Kini Nkechi gbọ ọrọ yii si, ni oun naa ba tun bọ si ori ayelujara Instagram tiẹ naa, to si sọ oko eebu si Lege Miami.
Amọ ni bayii, TAMPAN sọ pe oun kede aṣẹ idaduro naa fun awọn mejeeji "nitori pe iwa adojutini ti wọn n hu lori ayelujaran ta ẹrẹ si aṣọ apọnle ẹgbẹ naa.
"O si di dandan pe ki a ra ìyì wa to ti bajẹ pada."
Ijiya wo lo wa ninu aṣẹ ti TAMPAN kede?
Alaga ẹgbẹ awọn oludari ere, Damọla Ọlatunji sọ ninu atẹjade naa pe ko gbọdọ si oludari ere kankan, to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, ti yoo pe Nkechi Blessing ati Adams Kehinde si iṣẹ ere ṣiṣe.
"...oludari ere kankan to jẹ ọmọ ẹgbẹ yii, ko gbọdọ fun awọn osẹre mejeeji ni iṣẹ kankan botiwu ko kere mọ."
O ni oludari ere to ba fun wọn ni isẹ ṣe, tumọ si pe iru ẹni bẹẹ ti tapa si ofin ẹgbẹ TAMPAN, to jẹ baba fun gbogbo wọn.
"Eyi ti ijiya to yẹ si n duro o de."
Ẹwẹ, lẹyin eyi ni Nkechi Blessing fi fidio kan sori ayelujara ninu eyi to ti n beere pe ṣe oun ko ṣe pataki to lagbaye ni ati pe oun ko kere rara.