Baba Ijesha: Adewale Elesho, ààrẹ ANTP sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Baba Ijesha lẹ́yìn ò rẹyìn

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata labẹ aṣia ẹgbẹ Association of Nigerian Theater Arts Practictioners, ANTP, Alagba Adewale Ẹlẹshọ, ti ọpọ mọ si Elesho ẹnu n ja waya, naa ti da si ọrọ Baba Ijẹṣa bayii.

Ninu fidio kan to fi sori ayelujara, Elesho ni oun ko fẹ sọrọ lori oun to ṣẹlẹ si Baba Ijẹṣa bikoṣe bi awọn eeyan lawujọ to n pe ohun lọtun losi, lati da si ọrọ naa.

Eleso ni awọn yoo kọkọ le kọlọkọlọ lọ naa, ki awọn to fi abọ sori adiyẹ.

Elesho wa rawọ ẹbẹ si Princess, iya ọmọdebinrin ti wọn fẹsun kan pe Baba Ijesha huwa aṣemaṣe pẹlu rẹ, pe ko jeburẹ lori ọrọ naa, ki o si fi iyedenu nitori pe ọrọ naa ti gbona girigiri ju bi gbogbo awọn eeyan ṣe n sọ lọ.

O ni ki Princess o ro atimaaṣebọ oun ati Baba Ijesha ko fi iyedenu lori ọrọ naa, nitori oju ti ọrẹ mi oju ko timi, onitọun ni ko loju ti niyẹn.

Bakan naa ni gbajumọ oṣere alawada naa tun ke si awọn mọlẹbi ọmọdebinrin naa pe, lootọ ohun to ṣẹlẹ yii ko dun mọ ẹnikẹni ninu ṣugbọn bi a ba ni ka dana sun ejo bo ṣe gun to, afaimọ ka maa da ina sun ile.

"Mo bẹ awọn obi ọmọ ti nnkan ṣẹlẹ si, o jootọ o, ko joo tọ o, wọn ko gbọdọ maa pe eeyan lole, ko tun maa gbe ọmọ ẹran jo.

Ọlọrun nikan lo mọ ohun teeyan ko mọ"

Lẹyin to rọ gomina Babajide Sanwo-Olu lati bawọn foju sunnukun wo ọrọ naa, aarẹ ẹgbẹ oṣere ANTP naa tun ke sawọn ọlọpaa lati wadi ọrọ naa delẹ daadaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fi kun un pe, iṣẹlẹ naa fihan pe bi ko ti ṣe rọrun to lati ni orukọ rere, lo ṣe rọrun fun orukọ naa lati bajẹ lẹyin aṣemaṣe kan.