Wo àwọn orílẹ́-èdè tí o lè fi ìwé ìrìnnà Ghana wọlé sí láì gba físà

Ààrẹ South Africa àti ààrẹ Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti orileede South Africa ati Ghana ti pari ajọsọ nipa awọn orileede ti awọn to ba ni iwe irinna orileede wọn le wọle si lai gba fisa, irinajo lati lọ kaakiri agbaye ti wa bẹrẹ si rọrun bayii.

Idagbasoke yii ti wa di ohun ti awọn eeyan n sọ kaakiri igboro.

Anfaani tuntun yii lo wa fun awọn to ni iwe irinna ti a mọ si Passport, wi pe wọn le lọ kaakiri awọn orileede lai gba fisa laarin aadọrun-un ọjọ ninu ọdun.

Ọjọ kiini, oṣu kọkanla, ọdun ti a wa yii ni ajọsọ naa bẹrẹ, ati pe awọn to ba fẹ rin irinajo lati Ghana lọ South Africa gbọdọ le wa nibẹ fun aadọrun-un ọjọ lai ni erongba lati ṣiṣẹ ko to di pe wọn gbera.

Kii ṣe orileede yii nikan ni awọn to ba ni iwe irinna Ghana le wọ lai gba fisa.

Ni awọn orileede kan, ẹni to ba ni iwe irinna le wọle sibẹ lai gba fisa; l’awọn orileede miran, ẹni to ba ni iwe irinna le gba fisa lẹyin to ba ṣẹṣẹ debẹ tan.

Bẹẹ ni wọn tun le gba iwe aṣẹ ti wọn pe ni electronic travel authorization (eTA) nigba ti wọn ba wọle s’awọn orileede wọnyi.

Ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere lorileede Ghana lọjọ kẹwaa, oṣu karun-un, ọdun 2022 ṣafihan awọn orileede ti awọn to ba ni iwe irinna orileede Ghana le wọ lai gba fisa fun awọn oṣiṣẹ aṣọbode wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn orileede ti awọn ara Ghana wọ lai gba fisa ni:

  • Barbados
  • Burkina Faso
  • Mauritius
  • Nigeria
  • Seychelles
  • Benin
  • Kenya
  • Cape Verde
  • Lesotho
  • Ivory Coast
  • Tanzania
  • Senegal
  • Trinidad & Tobago
  • Liberia
  • Singapore
  • Niger
  • Uganda
  • Togo
  • Zimbabwe
  • Jamaica
  • Rwanda
  • Guyana
  • Saint Vincent & Grenadines

Ninu lẹta ti ileṣẹ to n sọrọ ilẹ okeere kọ ninu oṣu marun, ọdun 2022 naa kọ ni wọn tun ti ṣalaye awọn orileede ti awọn ọmọ Ghana lẹ wọ lai gba fisa, ṣugbọn ti kii ṣe fun gbogbo ẹni to ba ni iwe irinna.

Awọn orileede ti awọn to ba ni iwe irinna Diplomatic ati Service Passport le wọ lai gba fisa ree:

  • Brazil
  • Equatorial Guinea
  • China
  • Morocco
  • Cuba
  • Suriname
  • South Sudan
  • United Arab Emirates
  • Namibia
  • Venezuela
  • Hungary
  • Malta
  • India

Yatọ si pe awọn eeyan le wọ awọn orileede yii lai gba fisa, sibẹ awọn arinrin-ajo gbọdọ mọ pe iye igba ati asiko ti wọn maa lo nibẹ ni nnkan ṣe pẹlu ofin ati ilana orileede kọọkan.

Fun awọn orileede miran, ẹni to ba ni iwe irinna orileede Ghana le lọ gba fisa wọn nigba ti wọn ba debẹ.

Ni awọn igba miran, eeyan le lọ ba iwe irinna ori afẹfẹ tabi ti awọn ẹnubode ni kete ti wọn ba ti debẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, orileede kọọkan lo ni iye igba ati asiko ti fisa wọn yoo lo lọwọ ẹni ti wọn ba fun.

Ninu akọsilẹ Henley Passport Index to n ṣe igbelewọn awọn iwe irinna to jẹ ojulowo lagbaye, wọn ni ipo ọgọrin ni orileede Ghana wa ninu akọsilẹ wọn lọdun 2023.

Henley Passport Index, tun ka awọn orileede ti awọn to ba ni iwe irinna orileede Ghana le ti gba fisa ni kete ti wọn ba ti debẹ

Awọn orileede to maa n fun awọn to ba ni iwe irinna orileede Ghana ni fisa nigba ti wọn ba debẹ, iyẹn visa-on-arrival ni:

  • Palau islands
  • Burundi
  • Samoa
  • Comoros Island
  • Tuvalu
  • Djibouti
  • Iran
  • Ethiopia
  • Jordan
  • Mauritania
  • Saint Lucia
  • Somalia
  • Cambodia
  • Zambia
  • Maldives
  • Bolivia
  • Nicaragua

Fun awọn to ba fẹẹ wọ awọn orileede bii Pakistan ati Sri Lanka, wọn le gba iwe aṣẹ ti wọn n pe ni electronic travel authorization (eTA).

Eleyii ni iwe aṣẹ igbalode to maa n fun arinrin-ajo lanfaani lati wọ awọn orileede ti wọn kii tii gba visa.

Awọn eeyan le gba iwe aṣẹ naa lori ikanni ayelujara ko to di pe wọn bẹrẹ irin ajo wọn.

Anfaani fisa fun awọn to ba ni iwe irinna Ghana lọwọ yii yoo nii ṣe pẹlu asiko

Awọn miran le jẹ ọgbọn ọjọ, ọgọta ọjọ tabi aadọrin ọjọ, eyi si wa laarin adehun ti orileede Ghana ati orileede naa ti jọ ṣe.

Bi adehun fisa tabi ka sọ pe igbegidina ati awọn amuyẹ irin ajo laarin orileede Ghana pẹlu orileede naa ba yipada, a jẹ pe asiko fisa naa yoo yipada niyẹn.