Champlain Towers South: Èèyàn 99 ni wọ́n ṣì n wá nínú ilé tó wó ní Miami

O kere tan, eeyan kan ti ku, ti awọn to to mọkandinlọgọrun si di awati lẹyin ti ile alaja mejila kan, Champlain Towers wo lulẹ ni oru mọju Ọjọbọ, nilu Miami, Florida, lorilẹ-ede America.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri si ti n wa gbogbo abẹ awoku ile naa lati ṣawari awọn to ṣe e ṣe ko wa laaye, lara awọn ti wọn ti ri awọn kan yọ sita.

A ko ti i le sọ iye eeyan to wa ninu ile naa lasiko to wo, paapaa bo sẹ jẹ pe ile gbigbe ni.

Abala mẹta ni ile naa, to si ni aadoje ojule . Abala kan lo wo lulẹ.

Ile naa ti pe ogoji ọdun ti wọn kọ ọ.

Awọn oṣiṣẹ adoola sọ pe awọn n ṣiṣẹ karakara lati doola awọn to wa labẹ ile naa, nitori pe awọn n gburo awọn eeyan to n gba nkan labẹ àlàpà.

Katakata oloke si ni awọn oṣisẹ adoola n lo lati fi doola awọn eeyan to wa ni awọn ile to wa ni tosi ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn alaṣẹ sọ pe iṣẹ idoola naa ko le ya, to si lewu nitori pe awoku ile naa le wo lulẹ le wọn lori.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa sọju rẹ sọ fun akọroyin CNN pe bi ile naa sẹ wo dabi iṣẹlẹ 9/11, eyi to jẹ ikọlu si World Trade Center Twin Towers nilu New York lọdun 2001.

Ẹlomii ti iṣẹlẹ naa tun ṣoju rẹ sọpe ile naa kọkọ n mì, ko to o di pe o wo lulẹ.