You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Twitter Ban: Mínísítà Lai Mohammed fí ìkìlọ tuntun síta lórí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó n ló VPN
Minisita feto iroyin lorileede Naijiria Lai Mohammed tun ti da si ọrọ to gbode nipa iwọgile Twitter ni Naijiria.
Eyi to sọ laipẹ yi nii ṣe pẹlu ọrọ lilo VPN to jẹ ọna ẹburu tawọn ọmọ Naijiria fi n lo Twitter lati igba ti ijọba ti fofin de lilo rẹ.
Minisita Lai ṣe ọrọ naa bi ikilọ pe kawọn ọmọ Naijiria jawọ nibi lilo VPN.
O fi ọrọ yii lede lasiko to n dahun ibeere niwaju igbimọ ile aṣojuṣofin orileede Naijiria eyi to n gbẹjọ lori aṣẹ "ma lo Twitter" ti ijọba gbe kalẹ.
Lai Mohammed sọ pe''amọran mi si ẹnikẹni to baa n lo VPN ni pe ko jawọ nibẹ. Idi ni pe bi o ba lo VPN yoo tu gbogbo aṣiri data yin to fi mọ akoto akanti ifowopamọ yin''.
O ṣalaye pe ''awọn to ba ro wi pe awọn n ṣe Lai Mohammed nipa lilo VPN, ara wọn ni wọn n ṣe''.
Ilé ẹjọ́ ECOWAS pàṣẹ fún Naijiria láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter
Ajọ Ecowas ti ka ijọba Naijiria lọwọ ko pe ko gbọdọ fi ofin gbe ẹnikẹni tabi fi iya jẹ wọn nitori pe wọn lo ayeljuara Twitter ni Naijiria.
Ileeṣẹ ẹjọ Ecowas to wa ni Abuja lo pa aṣẹ na lasiko igbẹjọ akọkọ to waye lori ofin to de ayelujara naa lati ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa.
Aṣẹ yii waye lẹyin ti awọn ẹlẹgbẹjkgbẹ kan pe ẹjọ pe ọna lati fi ofin de ominira ọrọ sisọ ni igbesẹ ijọba bo sẹ fi ofin de lilo Twiter.
Ile ẹjọ na sọ pe anfaani araalu ni si Twitter mu ki o rọrun fun wọn lati le ma sọ ọrọ pẹlu ominira - ti igbesẹ to ba tako eyi si tumọ si titẹ ẹtọ ọmọniyan loju.
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Ọ̀run àpáàdì ń dúró de gbogbo ẹ̀yin aláìní ìrònúpìwàdà- Fani Kayode sí Gumi
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Orílẹ̀-èdè Amẹrika ké sí Naijiria láti fòpin sí fifi òfin de Twitter
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Àlàyé rè é lórí bí o ṣe lè gbá owó ìrànwọ́ N50bn COVID-19 tí CBN gbé jáde
- Lẹ́yìn ìjà tò gbẹ̀mí èèyàn bíi mẹ́ta, Makinde sè ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ àlákòóso Amọtẹkun
Ẹgbẹ to n ja fun akoyawọ nidi ọrọ aje, Socio-Economic Rights and Accountability Project, SERAP, ati awọn ọmọ Naijiria bi 170 lo pawọpọ , to si lọ si ile ẹjọ naa pe ko paṣẹ pe titẹ ẹtọ ọmọniyan loju ni igbesẹ ijọba Naijiria lori ọrọ Twitter, tumọ si labẹ ofin agbaye.
Ijọba fi ofin de lilo oju opo ayelujara Twitter lẹyin ti oju opo naa pa ọrọ kan ti Aarẹ Muhammadu Buhari kọ sibẹ, nitori pe o tako ilana lilo oju opo naa.
Nibi igbẹjọ naa to waye lori ayelujara ni ọjọ Iṣẹgun, agbẹjọro agba to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana, to ṣoju awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ naa bẹ ile ẹjọ naa lati fi ofin de ijọba Naijiria pe ko ma mu ẹnikẹni tabi fi iya jẹ wọn labẹ ofin nitoir pe wọn lo Twitter.
Ààrẹ Buhari fọwọ́sí kí Lai Mohammed, Fashola àti Malami jíròrò pẹlú 'Twitter'
Aawọ laarin orileede Naijiria ati ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ oju opo ayelujara Twitter ṣeeṣe ko ni iyanju lai pẹ yi.
Idi ni pe aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu ki ijọba Naijiria jiroro pẹlu ileeṣẹ naa.
Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti Minisita eto ibaraẹnisọrọ Lai Mohammed fi sita lọjọ Iṣẹgun.
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ẹ̀yin iléesẹ́ ìròyìn gbogbo ní Nàìjíríà, Ẹ dẹ́kun líló 'Twitter' bí bẹ́ẹ̀ kọ́...- NBC
- Iléesẹ́ Twitter ti ń bá ìjọba Nàìjíríà sọ̀rọ̀ papọ̀- Alhaji Lai Mohammed
- Twitter ní kí àwọn ènìyàn yí Password wọn padà
- Ìjọ RCCG kìí ṣe tí Nàíjíríà níkan, ìjọba kò lè dá wa dúró láti lo Twitter- Pásítọ̀ E. A. Adeboye
- O dí gbére! Iléeṣẹ́ Twitter tí ojú òpó Ààrẹ Donald Trump lórí ẹ̀rọ rẹ̀ pa
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
Gẹgẹ bi Segun Adeyemi to n gbẹnusọ fun Minisita Lai ti ṣe sọ, Lai Mohammed ni yoo dari ikọ Naijiria ti yoo jiroro pẹlu Twitter.
Awọn eeyan miran ti yoo kọwọrin pẹlu Minisita lati jiroro ni agbẹjọro agba Naijiria Abubakar Malami, Minista feto ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati eto ọrọ ajẹ ayelujara,Issa Ali Pantami.
Bẹẹ naa ni Minisita fọr ilẹ okere ati Minisita fọrọ iṣẹ ile ati oju ọna Babatunde Fashola yoo pẹlu igbimọ yi.
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Àlàyé rè é lórí bí o ṣe lè gbá owó ìrànwọ́ N50bn COVID-19 tí CBN gbé jáde
- Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Kò burú bí Twitter bá fòfin dè ìpolongo òṣèlú lójú òpó - Kayode Ogundamisi
- Orílẹ̀-èdè Amẹrika ké sí Naijiria láti fòpin sí fifi òfin de Twitter
Segun Adeyemi fi kun ọrọ rẹ ninu atẹjade naa pe Twitter lo bveere fun ijiroro pẹlu ijọba Naijiria.
Bi a ko ba gbagbe, ijọba Naijiria ti ṣaaju fofin de lilo Twitter nilẹ naa lẹyin ti oju opo naa yọ ọrọ ti aarẹ Buhari kọ.
Alaye ti ijọba ṣe lori igbesẹ yi ni pe iṣẹ Twitter le ṣe akoba fun igbe aaye alaafia ni Naijiria.